Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 14:6 - Bibeli Mimọ

6 Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè. Kò sí ẹni tí ó lè dé ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 14:6
57 Iomraidhean Croise  

Ohun gbogbo li a fifun mi lati ọdọ Baba mi wá: kò si si ẹniti o mọ̀ Ọmọ, bikoṣe Baba; bẹ̃ni kò si ẹniti o mọ̀ Baba bikoṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti Ọmọ fẹ fi i hàn fun.


Ọ̀rọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ.


Nitoripe nipasẹ Mose li a ti fi ofin funni, ṣugbọn ore-ọfẹ ati otitọ tipasẹ Jesu Kristi wá.


Ninu rẹ̀ ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀ araiye.


Emi si fun wọn ni ìye ainipẹkun; nwọn kì o si ṣegbé lailai, kò si si ẹniti o le já wọn kuro li ọwọ́ mi.


Nitorina Jesu tún wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Emi ni ilẹkun awọn agutan.


Emi ni ilẹkun: bi ẹnikan ba ba ọdọ mi wọle, on li a o gbà là, yio wọle, yio si jade, yio si ri koriko.


Nigba diẹ si i, aiye ki ó si ri mi mọ́; ṣugbọn ẹnyin ó ri mi: nitoriti emi wà lãye, ẹnyin ó wà lãye pẹlu.


EMI ni àjara tõtọ, Baba mi si ni oluṣọgba.


Nitorina Pilatu wi fun u pe, Njẹ iwọ ha ṣe ọba bi? Jesu dahùn wipe, Iwọ wipe, ọba li emi iṣe. Nitori eyi li a ṣe bí mi, ati nitori idi eyi ni mo si ṣe wá si aiye, ki emi ki o le jẹri si otitọ. Olukuluku ẹniti iṣe ti otitọ ngbọ́ ohùn mi.


Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti njí okú dide, ti o si nsọ wọn di ãye; bẹ̃li Ọmọ si nsọ awọn ti o fẹ di ãye.


Nitoripe onjẹ Ọlọrun li ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ti o si fi ìye fun araiye.


Emi ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai: onjẹ na ti emi o si fifunni li ara mi, fun ìye araiye.


Gẹgẹ bi Baba alãye ti rán mi, ti emi si ye nipa Baba: gẹgẹ bẹ̃li ẹniti o jẹ mi, on pẹlu yio yè nipa mi.


Nigbana ni Simoni Peteru da a lohùn wipe, Oluwa, Ọdọ tali awa o lọ? Iwọ li o ni ọ̀rọ ìye ainipẹkun.


Ẹ ó si mọ̀ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira.


Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bi ẹnikan ba pa ọ̀rọ mi mọ́, ki yio ri ikú lailai.


Ẹnyin si pa Olupilẹṣẹ ìye, ẹniti Ọlọrun si ti ji dide kuro ninu okú; ẹlẹri eyiti awa nṣe.


Kò si si igbala lọdọ ẹlomiran: nitori kò si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là.


O bẽre iwe lọwọ rẹ̀ si Damasku si awọn sinagogu pe, bi on ba ri ẹnikẹni ti mbẹ li Ọna yi, iba ṣe ọkunrin, tabi obinrin, ki on le mu wọn ni didè wá si Jerusalemu.


Ki emi ki o le ṣe iranṣẹ Jesu Kristi si awọn Keferi, lati ta ọrẹ ihinrere Ọlọrun, ki ọrẹ awọn Keferi ki o le di itẹwọgbà, ti a sọ di mimọ́ nipa Ẹmí Mimọ́.


Nipasẹ ẹniti awa si ti ri ọ̀na gbà nipa igbagbọ́ si inu ore-ọfẹ yi ninu eyi ti awa gbé duro, awa si nyọ̀ ni ireti ogo Ọlọrun.


Pe, gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ ti jọba nipa ikú, bẹni ki ore-ọfẹ si le jọba nipa ododo titi ìye ainipẹkun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa.


Bẹ̃li a si kọ ọ pe, Adamu ọkunrin iṣaju, alãye ọkàn li a da a; Adamu ikẹhin ẹmí isọnidãye.


Nitori nipa rẹ̀ li awa mejeji ti ni ọ̀na nipa Ẹmí kan sọdọ Baba.


Awọn ti iṣe ojiji ohun ti mbọ̀; ṣugbọn ti Kristi li ara.


Nitoripe ninu rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀kún Iwa-Ọlọrun ngbé li ara-iyara.


Nigbati Kristi, ẹniti iṣe ìye wa yio farahàn, nigbana li ẹnyin pẹlu o farahàn pẹlu rẹ̀ ninu ogo.


Nitorina o si le gba wọn là pẹlu titi de opin, ẹniti o ba tọ̀ Ọlọrun wá nipasẹ rẹ̀, nitoriti o mbẹ lãye titi lai lati mã bẹ̀bẹ fun wọn.


Ẹmí Mimọ́ ntọka eyi pé a kò ti iṣi ọ̀na ibi mimọ́ silẹ niwọn igbati agọ́ ekini ba duro.


Ani ẹnyin ti o ti ipasẹ rẹ̀ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú, ti o si fi ogo fun u; ki igbagbọ́ ati ireti nyin ki o le wà lọdọ Ọlọrun.


Ẹniti ẹnyin ntọ̀ bọ̀, bi si okuta ãye, ti a ti ọwọ́ enia kọ̀ silẹ nitõtọ, ṣugbọn lọdọ Ọlọrun, àṣayan, iyebiye,


Nitoriti Kristi pẹlu jìya lẹ̃kan nitori ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ fun awọn alaiṣõtọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹniti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di ãye ninu ẹmí:


Bi awa ba wipe awa kò li ẹ̀ṣẹ, awa tàn ara wa jẹ, otitọ kò si si ninu wa.


Ẹnikẹni ti o ba sẹ́ Ọmọ, on na ni kò gbà Baba: ṣugbọn ẹniti o ba jẹwọ Ọmọ, o gbà Baba pẹlu.


Awa si mọ̀ pe Ọmọ Ọlọrun de, o si ti fi òye fun wa, ki awa ki o le mọ̀ ẹniti iṣe otitọ, awa si mbẹ ninu ẹniti iṣe otitọ, ani ninu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Eyi li Ọlọrun otitọ, ati ìye ainipẹkun.


Eyi li ẹniti o wá, pẹlu omi ati ẹjẹ̀, ani Jesu Kristi, kì iṣe pẹlu omi nikan, bikoṣe pẹlu omi ati ẹ̀jẹ. Ẹmí li o si njẹri, nitoripe otitọ li Ẹmí.


Olukuluku ẹniti o ba nru ofin ti kò si duro ninu ẹkọ́ Kristi, kò gba Ọlọrun. Ẹniti o ba duro ninu ẹkọ́, on li o gbà ati Baba ati Ọmọ.


Ati lati ọdọ Jesu Kristi, ẹlẹri olõtọ, akọbi ninu awọn okú, ati alaṣẹ awọn ọba aiye. Ẹniti o fẹ wa, ti o si wẹ̀ wa ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa,


Mo si ri ọrun ṣí silẹ, si wo o, ẹṣin funfun kan; ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni a npe ni Olododo ati Olõtọ, ninu ododo li o si nṣe idajọ, ti o si njagun.


Bi a ba si ri ẹnikẹni ti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe ìye, a sọ ọ sinu adagun iná.


O si fi odò omi ìye kan han mi, ti o mọ́ bi kristali, ti nti ibi itẹ́ Ọlọrun ati ti Ọdọ-Agutan jade wá.


Ati Ẹmí ati iyawo wipe, Mã bọ̀. Ati ẹniti o ngbọ́ ki o wipe, Mã bọ̀. Ati ẹniti ongbẹ ngbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o ba si fẹ, ki o gbà omi ìye na lọfẹ.


Ati si angẹli ijọ ni Laodikea kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti ijẹ Amin wi, ẹlẹri olododo ati olõtọ, olupilẹṣẹ ẹda Ọlọrun.


Ati si angẹli ijọ ni Filadelfia kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti o jẹ mimọ́ ni wi, ẹniti iṣe olõtọ, ẹniti o ni kọkọrọ Dafidi, ẹniti o ṣí, ti kò si ẹniti yio tì; ẹniti o si tì, ti kò si ẹniti yio ṣí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan