Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 14:12 - Bibeli Mimọ

12 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, iṣẹ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi jù wọnyi lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ yóo ṣe àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe; yóo tilẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó ju ìwọ̀nyí lọ, nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú; iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe; nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 14:12
28 Iomraidhean Croise  

Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́, ti ẹ kò ba si ṣiyemeji, ẹnyin kì yio ṣe kìki eyi ti a ṣe si igi ọpọtọ yi, ṣugbọn bi ẹnyin ba tilẹ wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ́ sinu okun, yio ṣẹ.


O si ri igi ọpọtọ kan li òkere ti o li ewé, o wá, bi bọya on le ri ohun kan lori rẹ̀: nigbati o si wá si idi rẹ̀, ko ri ohun kan, bikoṣe ewé; nitori akokò eso ọpọtọ kò ti ito.


Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ́ lọ; Li orukọ mi ni nwọn o ma lé awọn ẹmi èṣu jade; nwọn o si ma fi ède titun sọ̀rọ;


Ẹnyin sá ti gbọ́ bi mo ti wi fun nyin pe, Emi nlọ, emi ó si tọ̀ nyin wá. Ibaṣepe ẹnyin fẹràn mi, ẹnyin iba yọ̀ nitori emi nlọ sọdọ Baba: nitori Baba mi tobi jù mi lọ.


Ṣugbọn otitọ li emi nsọ fun nyin; anfani ni yio jẹ fun nyin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò ba lọ, Olutunu kì yio tọ̀ nyin wá: ṣugbọn bi mo ba lọ, emi o rán a si nyin.


Nitori ninu eyi ni ọ̀rọ na fi jẹ otitọ: Ẹnikan li o fọnrugbin, ẹlomiran li o si nkòre jọ.


Nitori Baba fẹràn Ọmọ, o si fi ohun gbogbo ti on tikararẹ̀ nṣe hàn a: on ó si fi iṣẹ ti o tobi ju wọnyi lọ hàn a, ki ẹnu ki o le yà nyin.


Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Niwọn igba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin, emi o si lọ sọdọ ẹniti o rán mi.


(Ṣugbọn o sọ eyi niti Ẹmí, ti awọn ti o gbà a gbọ́ mbọ̀wá gbà: nitori a kò ti ifi Ẹmí Mimọ́ funni; nitoriti a kò ti iṣe Jesu logo.)


Nitori nwọn gbọ́, nwọn nfọ onirũru ède, nwọn si nyìn Ọlọrun logo. Nigbana ni Peteru dahùn wipe,


O si nṣe eyi li ọjọ pipọ. Ṣugbọn nigbati inu Paulu bajẹ, ti o si yipada, o wi fun ẹmí na pe, Mo paṣẹ fun ọ li orukọ Jesu Kristi kí o jade kuro lara rẹ̀. O si jade ni wakati kanna.


Tobẹ̃ ti a fi nmu gèle ati ibantẹ́ ara rẹ̀ tọ̀ awọn olokunrun lọ, arùn si fi wọn silẹ, ati awọn ẹmi buburu si jade kuro lara wọn.


Nitorina bi a ti fi ọwọ́ ọtún Ọlọrun gbe e ga, ti o si ti gbà ileri Ẹmí Mimọ́ lati ọdọ Baba, o tú eyi silẹ, ti ẹnyin ri, ti ẹ si gbọ́.


Nitorina awọn ti o si fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ rẹ̀ a baptisi wọn: li ọjọ na a si kà ìwọn ẹgbẹdogun ọkàn kún wọn.


Wipe, Kili a o ti ṣe awọn ọkunrin wọnyi? ti pe iṣẹ àmi ti o daju ti ọwọ́ wọn ṣe, o hàn gbangba fun gbogbo awọn ti ngbé Jerusalemu; awa kò si le sẹ́ ẹ.


Agbara nla li awọn aposteli si fi njẹri ajinde Jesu Oluwa; ore-ọfẹ pipọ si wà lori gbogbo wọn.


Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na gbagbọ́; iye awọn ọkunrin na si to ẹgbẹ̃dọgbọn.


Tobẹ̃ ti nwọn ngbé awọn abirùn jade si igboro, ti nwọn ntẹ́ wọn si ori akete ati ohun ibĩrọgbọku, pe bi Peteru ba nkọja ki ojiji rẹ̀ tilẹ le ṣijibò omiran ninu wọn.


Ọ̀rọ Ọlọrun si gbilẹ; iye awọn ọmọ-ẹhin si pọ̀ si i gidigidi ni Jerusalemu; ọ̀pọ ninu ẹgbẹ awọn alufa si fetisi ti igbagbọ́ na.


Nitori ọpọ ninu awọn ti o ni ẹmi àimọ́ ti nkigbe lohùn rara, jade wá, ati ọpọ awọn ti ẹ̀gba mbajà, ati awọn amọ́kún, a si ṣe dida ara wọn.


Peteru si wi fun u pe, Enea, Jesu Kristi mu ọ larada: dide, ki o si tún akete rẹ ṣe. O si dide lojukanna.


Ṣugbọn Peteru ti gbogbo wọn sode, o si kunlẹ, o si gbadura; o si yipada si okú, o ni, Tabita, dide. O si là oju rẹ̀: nigbati o si ri Peteru, o dide joko.


Nipa agbara iṣẹ-àmi ati iṣẹ-iyanu, nipa agbara Ẹmí Ọlọrun; tobẹ̃ lati Jerusalemu ati yiká kiri ani titi fi de Illirikoni, mo ti wasu ihinrere Kristi ni kikun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan