Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 14:1 - Bibeli Mimọ

1 Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹ gbà mi gbọ́ pẹlu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú. Ẹ gba Ọlọrun gbọ́, kí ẹ sì gba èmi náà gbọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú: ẹ gba Ọlọ́run gbọ́, kí ẹ sì gbà mí gbọ́ pẹ̀lú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 14:1
37 Iomraidhean Croise  

Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun: nitoriti emi o sa ma yìn i sibẹ, ẹniti iṣe iranlọwọ oju mi, ati Ọlọrun mi.


Emi wipe, Eyi li ailera mi! eyi li ọdun ọwọ ọtún Ọga-ogo!


Iwọ o pa a mọ li alafia pipé, ọkàn ẹniti o simi le ọ: nitoriti o gbẹkẹle ọ.


Emi iba le tù ara mi ninu, ninu ikãnu mi? ọkàn mi daku ninu mi!


Njẹ nigbati Jesu ri i, ti o nsọkun, ati awọn Ju ti o ba a wá nsọkun pẹlu rẹ̀, o kerora li ọkàn rẹ̀, inu rẹ̀ si bajẹ,


Nisisiyi li a npọ́n ọkàn mi loju; kili emi o si wi? Baba, gbà mi kuro ninu wakati yi: ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe wá si wakati yi.


Jesu si kigbe o si wipe, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, emi kọ li o gbàgbọ́, ṣugbọn ẹniti o rán mi.


Lati isisiyi lọ mo sọ fun nyin ki o to de, pe nigbati o ba de, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́ pe emi ni.


Titi di isisiyi ẹ kò ti ibère ohunkohun li orukọ mi: ẹ bère, ẹ o si ri gbà, ki ayọ̀ nyin ki o le kún.


Nkan wọnyi ni nwọn o si ṣe, nitoriti nwọn kò mọ̀ Baba, nwọn kò si mọ̀ mi.


Ṣugbọn nitori mo sọ nkan wọnyi fun nyin, ibinujẹ kún ọkàn nyin.


Ki gbogbo enia ki o le mã fi ọlá fun Ọmọ gẹgẹ bi nwọn ti nfi ọlá fun Baba. Ẹniti kò ba fi ọlá fun Ọmọ, kò fi ọlá fun Baba ti o rán a.


Eyi si ni ifẹ ẹniti o rán mi, pe ẹnikẹni ti o ba rí Ọmọ, ti o ba si gbà a gbọ́, ki o le ni iye ainipẹkun: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.


Kaka bẹ ẹ, ẹnyin iba kuku darijì i, ki ẹ si tù u ninu, lọnakọna ki ọpọlọpọ ibanujẹ má bã bò iru enia bẹ̃ mọlẹ.


Nitori eyi, emi pẹlu, nigbati mo ti gburó igbagbọ ti mbẹ larin nyin ninu Jesu Oluwa, ati ifẹ nyin si gbogbo awọn enia mimọ́,


Ki ọkàn nyin ki o máṣe tete mì, tabi ki ẹ máṣe jaiya, yala nipa ẹmí, tabi nipa ọ̀rọ, tabi nipa iwe bi lati ọdọ wa wá, bi ẹnipe ọjọ Oluwa de.


Ani ẹnyin ti o ti ipasẹ rẹ̀ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú, ti o si fi ogo fun u; ki igbagbọ́ ati ireti nyin ki o le wà lọdọ Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan