Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 13:9 - Bibeli Mimọ

9 Simoni Peteru wi fun u pe, Oluwa, kì iṣe ẹsẹ mi nikan, ṣugbọn ati ọwọ́ ati ori mi pẹlu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Simoni Peteru bá sọ fún un pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Oluwa, ẹsẹ̀ mi nìkan kọ́, ati ọwọ́ ati orí mi ni kí o fọ̀ pẹlu.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Simoni Peteru wí fún ún pé, “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan, ṣùgbọ́n àti ọwọ́ àti orí mi pẹ̀lú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 13:9
9 Iomraidhean Croise  

Emi o wẹ̀ ọwọ mi li ailẹṣẹ: bẹ̃li emi o si yi pẹpẹ rẹ ká, Oluwa.


Wẹ̀ mi li awẹmọ́ kuro ninu aiṣedede mi, ki o si wẹ̀ mi nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi.


Fi ewe-hissopu fọ̀ mi, emi o si mọ́: wẹ̀ mi, emi o si fún jù ẹ̀gbọn-owu lọ.


Jerusalemu! wẹ ọkàn rẹ kuro ninu buburu, ki a ba le gba ọ là. Yio ti pẹ to ti iro asan yio wọ̀ si inu rẹ.


Nigbati Pilatu ri pe, on ko le bori li ohunkohun, ṣugbọn pe a kuku sọ gbogbo rẹ̀ di ariwo, o bu omi, o si wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ li oju ijọ, o wipe, Ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ enia olõtọ yi: ẹ mã bojuto o.


Jesu wi fun u pe, Ẹniti a ti wẹ̀ kò tun fẹ ju ki a ṣan ẹsẹ rẹ̀, ṣugbọn o mọ́ nibi gbogbo: ẹnyin si mọ́, ṣugbọn kì iṣe gbogbo nyin.


Peteru wi fun u pe, Iwọ kì yio wẹ̀ mi li ẹsẹ lai. Jesu da a lohùn pe, Bi emi kò bá wẹ̀ ọ, iwọ kò ni ìpin lọdọ mi.


Ẹ jẹ ki a fi otitọ ọkàn sunmọ tosi ni ẹ̀kún igbagbọ́, ki a si wẹ̀ ọkàn wa mọ́ kuro ninu ẹri-ọkàn buburu, ki a si fi omi mimọ́ wẹ̀ ara wa nù.


Apẹrẹ eyiti ngbà nyin là nisisiyi pẹlu, ani baptismu, kì iṣe ìwẹ ẽri ti ara nù, bikoṣe idahùn ọkàn rere sipa Ọlọrun, nipa ajinde Jesu Kristi:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan