Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 13:5 - Bibeli Mimọ

5 Lẹhinna o bù omi sinu awokòto kan, o si bẹ̀rẹ si ima wẹ̀ ẹsẹ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si nfi gèle ti o fi di àmure nù wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 ó bu omi sinu àwokòtò kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ń fi aṣọ ìnura tí ó lọ́ mọ́ ìbàdí nù wọ́n lẹ́sẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú àwokòtò kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń fi aṣọ ìnura tí ó fi di àmùrè nù wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 13:5
30 Iomraidhean Croise  

Jẹ ki a mu omi diẹ wá nisisiyi, ki ẹnyin ki o si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ki ẹnyin ki o si simi labẹ igi:


O si wipe, Kiyesi i nisisiyi, ẹnyin oluwa mi, emi bẹ̀ nyin, ẹ yà si ile ọmọ-ọdọ nyin, ki ẹ si wọ̀, ki ẹ si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ẹnyin o si dide ni kùtukutu, ki ẹ si ma ba ti nyin lọ. Nwọn si wipe, Ndao; ṣugbọn awa o joko ni igboro li oru oni.


Ọkunrin na si mú awọn ọkunrin na wá si ile Josefu, o si fun wọn li omi, nwọn si wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn; o si fun awọn kẹtẹkẹtẹ wọn li ohun jijẹ.


Jehoṣafati si wipe, Kò ha si woli Oluwa kan nihin, ti awa iba ti ọdọ rẹ̀ bère lọwọ Oluwa? Ọkan ninu awọn iranṣẹ ọba Israeli dahùn wipe, Eliṣa, ọmọ Ṣafati ti ntú omi si ọwọ Elijah mbẹ nihinyi.


Wẹ̀ mi li awẹmọ́ kuro ninu aiṣedede mi, ki o si wẹ̀ mi nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi.


Iwọ o si mú Aaroni pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, iwọ o si fi omi wẹ̀ wọn.


Ẹ wẹ̀, ki ẹ mọ́; mu buburu iṣe nyin kuro niwaju oju mi: dawọ duro lati ṣe buburu;


Nigbana ni emi o fi omi mimọ́ wọ́n nyin, ẹnyin o si mọ́: emi o si wẹ̀ nyin mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin nyin ati kuro ninu gbogbo oriṣa nyin.


Ki ẹniti a o wẹ̀numọ́ nì ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si fá gbogbo irun ori rẹ̀ kuro, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o le mọ́: lẹhin eyinì ni ki o wọ̀ ibudó, ṣugbọn ki o gbé ẹhin ode agọ́ rẹ̀ ni ijọ́ meje.


LI ọjọ na isun kan yio ṣi silẹ fun ile Dafidi ati fun awọn ara Jerusalemu, fun ẹ̀ṣẹ ati fun ìwa aimọ́.


O si duro tì i lẹba ẹsẹ rẹ̀ lẹhin, o nsọkun, o si bẹ̀rẹ si ifi omije wẹ̀ ẹ li ẹsẹ, o si nfi irun ori rẹ̀ nù u nù, o si nfi ẹnu kò o li ẹsẹ, o si nfi ororo kùn wọn.


O si yipada si obinrin na, o wi fun Simoni pe, Iwọ ri obinrin yi? Emi wọ̀ ile rẹ, omi wiwẹ̀ ẹsẹ iwọ kò fifun mi: ṣugbọn on, omije li o fi nrọjo si mi li ẹsẹ, irun ori rẹ̀ li o fi nnù wọn nù.


Jesu wi fun u pe, Ẹniti a ti wẹ̀ kò tun fẹ ju ki a ṣan ẹsẹ rẹ̀, ṣugbọn o mọ́ nibi gbogbo: ẹnyin si mọ́, ṣugbọn kì iṣe gbogbo nyin.


Nigbana li o de ọdọ Simoni Peteru. On si wi fun u pe, Oluwa, iwọ nwẹ̀ mi li ẹsẹ?


Peteru wi fun u pe, Iwọ kì yio wẹ̀ mi li ẹsẹ lai. Jesu da a lohùn pe, Bi emi kò bá wẹ̀ ọ, iwọ kò ni ìpin lọdọ mi.


Ṣugbọn ọkan ninu awọn ọmọ-ogun na fi ọ̀kọ gún u li ẹgbẹ, lojukanna ẹ̀jẹ ati omi si tú jade.


Njẹ nisisiyi kini iwọ nduro de? Dide, ki a si baptisi rẹ, ki o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ nù, ki o si mã pè orukọ Oluwa.


Bẹ̃ li awọn ẹlomiran ninu nyin si ti jẹ rí: ṣugbọn a ti wẹ̀ nyin nù, ṣugbọn a ti sọ nyin di mimọ́, ṣugbọn a ti da nyin lare li orukọ Jesu Kristi Oluwa, ati nipa Ẹmí Ọlọrun wa.


Ki on ki o le sọ ọ di mimọ́ lẹhin ti a ti fi ọ̀rọ wẹ ẹ mọ́ ninu agbada omi,


Ẹniti a jẹri rẹ̀ fun iṣẹ rere; bi o ba ti ntọ́ ọmọ ri, bi o ba ti ngba alejò, bi o bá ti nwẹ ẹsẹ awọn enia mimọ́, bi o ba ti nràn awọn olupọnju lọwọ, bi o ba ti nlepa iṣẹ rere gbogbo.


Ẹ jẹ ki a fi otitọ ọkàn sunmọ tosi ni ẹ̀kún igbagbọ́, ki a si wẹ̀ ọkàn wa mọ́ kuro ninu ẹri-ọkàn buburu, ki a si fi omi mimọ́ wẹ̀ ara wa nù.


Ṣugbọn bi awa ba nrìn ninu imọlẹ, bi on ti mbẹ ninu imọlẹ, awa ní ìdapọ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ ni nwẹ̀ wa nù kuro ninu ẹṣẹ gbogbo.


Eyi li ẹniti o wá, pẹlu omi ati ẹjẹ̀, ani Jesu Kristi, kì iṣe pẹlu omi nikan, bikoṣe pẹlu omi ati ẹ̀jẹ. Ẹmí li o si njẹri, nitoripe otitọ li Ẹmí.


Ati lati ọdọ Jesu Kristi, ẹlẹri olõtọ, akọbi ninu awọn okú, ati alaṣẹ awọn ọba aiye. Ẹniti o fẹ wa, ti o si wẹ̀ wa ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa,


Mo si wi fun u pe, Oluwa mi, Iwọ li o le mọ̀. O si wi fun mi pe, Awọn wọnyi li o jade lati inu ipọnju nla, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn, nwọn si sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na.


Bẹ̃li o mú u wá sinu ile rẹ̀, o si fi onjẹ fun awọn kẹtẹkẹtẹ: nwọn wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, nwọn jẹ nwọn si mu.


O si dide, o si dojubolẹ, o si wipe, Wõ, jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ ki o jẹ iranṣẹ kan lati ma wẹ ẹsẹ awọn iranṣẹ oluwa mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan