Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 13:19 - Bibeli Mimọ

19 Lati isisiyi lọ mo sọ fun nyin ki o to de, pe nigbati o ba de, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́ pe emi ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

19 Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè mọ ẹni tí èmi í ṣe nígbà tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ tán.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

19 “Láti ìsinsin yìí lọ ni mo wí fún un yín kí ó tó dé, pé nígbà tí ó bá dé, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé èmi ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 13:19
15 Iomraidhean Croise  

Fi ohun ti mbọ̀ lẹhìn eyi hàn, ki awa ki o le mọ̀ pe ọlọrun ni nyin: nitõtọ, ẹ ṣe rere, tabi ẹ ṣe buburu, ki ẹ̀ru le bà wa, ki a le jumọ ri i.


Ẹnyin li ẹlẹri mi, ni Oluwa wi, ati iranṣẹ mi ti mo ti yàn: ki ẹnyin ki o le mọ̀, ki ẹ si gbà mi gbọ́ ki o si ye nyin pe, Emi ni; a kò mọ̀ Ọlọrun kan ṣãju mi, bẹ̃ni ọkan kì yio si hù lẹhin mi.


Li atetekọṣe ni mo tilẹ ti sọ fun ọ; ki o to de ni emi ti fihàn ọ: ki iwọ má ba wipe, Oriṣa mi li o ṣe wọn, ati ere mi gbigbẹ́, ati ere mi didà li o ti pa wọn li aṣẹ.


KIYESI i, Emi o rán onṣẹ mi, yio si tún ọ̀na ṣe niwaju mi: ati Oluwa, ti ẹnyin nwá, yio de li ojijì si tempili rẹ̀, ani onṣẹ majẹmu na, ti inu nyin dùn si; kiye si i, o mbọ̀ wá, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.


O si wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a mã reti ẹlomiran?


Wo o, mo wi fun nyin tẹlẹ.


Yio si pada di ẹrí fun nyin.


Johanu si jẹri rẹ̀ o si kigbe, wipe, Eyi ni ẹniti mo sọrọ rẹ̀ pe, Ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, o pọ̀ju mi lọ: nitori o wà ṣiwaju mi.


Emi si ti sọ fun nyin nisisiyi ki o to ṣẹ, pe nigbati o ba ṣẹ, ki ẹ le gbagbọ́.


Ṣugbọn nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, pe nigbati wakati wọn ba de, ki ẹ le ranti wọn pe mo ti wi fun nyin. Ṣugbọn emi ko sọ nkan wọnyi fun nyin lati ipilẹṣẹ wá, nitoriti mo wà pẹlu nyin.


Jesu wi fun u pe, Emi ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi li on.


Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Nigbati ẹ ba gbé Ọmọ-enia soke, nigbana li ẹ o mọ̀ pe, emi ni, ati pe emi kò dá ohunkohun ṣe fun ara mi; ṣugbọn bi Baba ti kọ́ mi, emi nsọ nkan wọnyi.


Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ki Abrahamu to wà, emi ti wà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan