Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 13:13 - Bibeli Mimọ

13 Ẹnyin npè mi li Olukọni ati Oluwa: ẹnyin wi rere; bẹ̃ni mo jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 Ẹ̀ ń pè mí ní Olùkọ́ni ati Oluwa. Ó dára, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Ẹ̀yin ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ ẹ̀yin wí rere; bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 13:13
18 Iomraidhean Croise  

Oluwa si wi fun mi pe, iwọ riran rere, nitori ti emi o kiye si ọ̀rọ mi lati mu u ṣẹ.


Ani gẹgẹ bi Ọmọ-enia kò ti wá ki a ṣe iranṣẹ fun u, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe iràpada ọpọlọpọ enia.


O si wi fun u pe, Iwọ dahùn rere: ṣe eyi, iwọ o si yè.


Ẽsitiṣe ti ẹnyin npè mi li Oluwa, Oluwa, ti ẹnyin kò si ṣe ohun ti mo wi?


Simoni dahùn o si wipe, mo ṣebi ẹniti o darijì jù ni. O si wi fun u pe, O wi i 're.


(Maria na li ẹniti o fi ororo ikunra kùn Oluwa, ti o si fi irun ori rẹ̀ nù ẹsẹ rẹ̀ nù, arakunrin rẹ̀ ni Lasaru iṣe, ara ẹniti kò dá.)


Nigbati o si ti wi eyi tan, o lọ, o si pè Maria arabinrin rẹ̀ sẹhin wipe, Olukọni de, o si npè ọ.


Nitorina awọn arabinrin rẹ̀ ranṣẹ si i, wipe, Oluwa, wo o, ara ẹniti iwọ fẹran kò da.


Nitorina mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe, kò si ẹniti nsọ̀rọ nipa Ẹmí Ọlọrun ki o wipe ẹni ifibu ni Jesu: ati pe, kò si ẹniti o le wipe, Oluwa ni Jesu, bikoṣe nipa Ẹmí Mimọ́.


Ṣugbọn fun awa Ọlọrun kan ni mbẹ, Baba, lọwọ ẹniti ohun gbogbo ti wá, ati ti ẹniti gbogbo wa iṣe; ati Oluwa kanṣoṣo Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ati awa nipasẹ rẹ̀.


Ati ẹnyin oluwa, ẹ mã ṣe ohun kanna si wọn, ẹ mã din ibẹru nyin kù; bi ẹnyin ti mọ pe Oluwa ẹnyin tikaranyin si mbẹ li ọrun; kò si si ojuṣãju enia lọdọ rẹ̀.


Ati pe ki gbogbo ahọn ki o mã jẹwọ pe, Jesu Kristi ni Oluwa, fun ogo Ọlọrun Baba.


Nitõtọ laiṣe ani-ani mo si kà ohun gbogbo si òfo nitori itayọ ìmọ Kristi Jesu Oluwa mi: nitori ẹniti mo ti ṣòfo ohun gbogbo, mo si kà wọn si igbẹ́, ki emi ki o le jère Kristi,


Iwọ gbagbọ́ pe Ọlọrun kan ni mbẹ; o dara: awọn ẹmí èṣu pẹlu gbagbọ́, nwọn si warìri.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan