Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 13:10 - Bibeli Mimọ

10 Jesu wi fun u pe, Ẹniti a ti wẹ̀ kò tun fẹ ju ki a ṣan ẹsẹ rẹ̀, ṣugbọn o mọ́ nibi gbogbo: ẹnyin si mọ́, ṣugbọn kì iṣe gbogbo nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí ó bá ti wẹ̀ nílé, tí ó bá jáde, kò sí ohun tí ó kù jù pé kí á fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, gbogbo ara rẹ̀ á wá di mímọ́. Ẹ̀yin mọ́, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo yín.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí a wẹ̀ kò tún fẹ́ ju kí a ṣan ẹsẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó mọ́ níbi gbogbo: ẹ̀yin sì mọ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo yín.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 13:10
23 Iomraidhean Croise  

Nitoriti kò si olõtọ enia lori ilẹ, ti nṣe rere ti kò si dẹṣẹ.


Iwọ li ẹwà gbogbo, olufẹ mi; kò si abawọ́n lara rẹ!


Li ọjọ wọnni, ati li akoko na, li Oluwa wi, a o wá aiṣedẽde Israeli kiri, ṣugbọn kì o si mọ́; ati ẹ̀ṣẹ Juda, a kì o si ri wọn: nitori emi o dariji awọn ti mo mu ṣẹkù.


Ati ẹniti o jọwọ ewurẹ nì lọwọ lọ fun Asaseli, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin eyinì ni ki o wá si ibudó.


Ati ẹniti o sun wọn ni ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin eyinì ni ki o wá si ibudó.


Dari gbese wa jì wa, bi awa ti ndarijì awọn onigbese wa.


Kì iṣe ti gbogbo nyin ni mo nsọ: emi mọ̀ awọn ti mo yàn: ṣugbọn ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, Ẹniti mba mi jẹun pọ̀ si gbé gigĩsẹ rẹ̀ si mi.


Simoni Peteru wi fun u pe, Oluwa, kì iṣe ẹsẹ mi nikan, ṣugbọn ati ọwọ́ ati ori mi pẹlu.


Ẹnyin mọ́ nisisiyi nitori ọ̀rọ ti mo ti sọ fun nyin.


Nitorina bi ẹnikẹni ba wà ninu Kristi, o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun.


Nitori o ti fi i ṣe ẹ̀ṣẹ nitori wa, ẹniti kò mọ̀ ẹ̀ṣẹkẹṣẹ rí; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ̀.


NITORINA, ẹnyin olufẹ, bi a ti ni ileri wọnyi, ẹ jẹ ki a wẹ̀ ara wa mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin ti ara ati ti ẹmí, ki a mã sọ ìwa mimọ́ di pipé ni ìbẹru Ọlọrun.


Ki Ọlọrun alafia tikararẹ̀ ki o sọ nyin di mimọ́ patapata; ki a si pa ẹmí ati ọkàn ati ara nyin mọ́ patapata li ailabukù ni ìgba wíwa Oluwa wa Jesu Kristi.


Eyiti o wà ninu ohun jijẹ ati ohun mimu ati onirũru ìwẹ, ti iṣe ìlana ti ara nikan ti a fi lelẹ titi fi di igba atunṣe.


Nitori ninu ohun pipọ ni gbogbo wa nṣì i ṣe. Bi ẹnikan kò ba ṣì i ṣe ninu ọ̀rọ, on na li ẹni pipé, on li o si le kó gbogbo ara ni ijanu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan