Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 12:5 - Bibeli Mimọ

5 Ẽṣe ti a kò tà ororo ikunra yi ni ọ̃durun owo idẹ ki a si fifun awọn talakà?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 “Kí ló dé tí a kò ta òróró yìí ní nǹkan bí ọọdunrun (300) owó fadaka, kí á pín in fún àwọn talaka?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 “Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 12:5
16 Iomraidhean Croise  

Njẹ nisisiyi lati ãfin ọba wá li a sa ti mbọ́ wa, kò si yẹ fun wa lati ri àbuku ọba, nitorina li awa ṣe ranṣẹ lati wi fun ọba daju;


Ṣugbọn on wipe, Ẹnyin ọlẹ, ẹnyin ọlẹ: nitorina li ẹ ṣe wipe, Jẹ ki a lọ ṣẹbọ si OLUWA.


Ati iye briki ti nwọn ti ima ṣe ni ìgba atẹhinwá, on ni ki ẹnyin bù fun wọn; ẹnyin kò gbọdọ ṣẹ nkan kù kuro nibẹ̀: nitoriti nwọn nṣe imẹlẹ; nitorina ni nwọn ṣe nke wipe, Jẹ ki a lọ rubọ si Ọlorun wa.


Ti nwipe, Nigbawo ni oṣù titún yio pari, ki awa ba le ta ọkà? ati ọjọ isimi, ki awa ba le ṣi alikama silẹ, ki a si ṣe ìwọn efà kere, ati ìwọn ṣekeli tobi, ki a si ma fi ẹ̀tan yi ìwọn padà?


Ṣugbọn nigbati ọmọ-ọdọ na jade lọ, o si ri ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ ẹgbẹ rẹ̀, ti o jẹ ẹ li ọgọrun owo idẹ: o gbé ọwọ́ le e, o fún u li ọrùn, o wipe, San gbese ti iwọ jẹ mi.


Nigbati o si ba awọn alagbaṣe pinnu rẹ̀ si owo idẹ kọkan li õjọ, o rán wọn lọ sinu ọgba ajara rẹ̀.


Ẹ tà ohun ti ẹnyin ni, ki ẹnyin ki o si tọrẹ ãnu; ki ẹnyin ki o si pèse àpo fun ara nyin, ti kì igbó, iṣura li ọrun ti kì itán, nibiti olè kò le sunmọ, ati ibiti kòkoro kì iba a jẹ.


Nigbati Jesu si gbọ́ eyi, o wi fun u pe, Ohun kan li o kù fun ọ sibẹ: lọ ità ohun gbogbo ti o ni, ki o si pín i fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá, ki o mã tọ̀ mi lẹhin.


Ẽṣe ti iwọ si nwò ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ, ṣugbọn iwọ kò kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ?


Nigbana li ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni, ẹniti yio fi i hàn, wipe,


Ṣugbọn o wi eyi, ki iṣe nitoriti o náni awọn talakà; ṣugbọn nitoriti iṣe olè, on li o si ni àpo, a si ma gbé ohun ti a fi sinu rẹ̀.


Nitori awọn miran ninu wọn rò pe, nitori Judasi li o ni àpo, ni Jesu fi wi fun u pe, Rà nkan wọnni ti a kò le ṣe alaini fun ajọ na; tabi ki o le fi nkan fun awọn talakà.


Filippi da a lohùn pe, Akara igba owo idẹ ko to fun wọn, ti olukuluku wọn iba fi mu diẹ-diẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan