Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 12:2 - Bibeli Mimọ

2 Nwọn si se ase-alẹ fun u nibẹ: Marta si nṣe iranṣẹ: ṣugbọn Lasaru jẹ ọkan ninu awọn ti o joko nibi tabili pẹlu rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Wọ́n se àsè kan fún un níbẹ̀. Mata ń ṣe ètò gbígbé oúnjẹ kalẹ̀; Lasaru wà ninu àwọn tí ó ń bá Jesu jẹun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀: Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́: ṣùgbọ́n Lasaru Jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 12:2
12 Iomraidhean Croise  

Ji afẹfẹ ariwa; si wá, iwọ ti gusu; fẹ́ sori ọgbà mi, ki õrun inu rẹ̀ le fẹ́ jade. Jẹ ki olufẹ mi wá sinu ọgbà rẹ̀, ki o si jẹ eso didara rẹ̀.


Nigbati Jesu si wà ni Betani ni ile Simoni adẹtẹ̀,


Nigbati o si wà ni Betani ni ile Simoni adẹtẹ̀, bi o ti joko tì onjẹ, obinrin kan ti o ni oruba alabasta ororo ikunra nardi iyebiye, o wá, o si fọ́ orúba na, o si ndà a si i lori.


Ibukun ni fun awọn ọmọ-ọdọ wọnni nigbati oluwa na ba de ti yio ba ki nwọn ki o ma ṣọna: lõtọ ni mo wi fun nyin, yio di ara rẹ̀ li amure, yio si mu wọn joko lati jẹun, yio si jade wá lati ṣe iranṣẹ fun wọn.


Nigbana li o si wi fun alase ti o pè e pe, Nigbati iwọ ba se àse ọsán, tabi àse alẹ, má pè awọn ọrẹ́ rẹ, tabi awọn arakunrin rẹ, tabi awọn ibatan rẹ, tabi awọn aladugbo rẹ ọlọrọ̀; nitori ki nwọn ki o má ṣe pè ọ ẹ̀wẹ lati san ẹsan fun ọ.


Nitori tali o pọ̀ju, ẹniti o joko tì onjẹ, tabi ẹniti o nṣe iranṣẹ? ẹniti o joko tì onjẹ ha kọ́? ṣugbọn emi mbẹ larin nyin bi ẹniti nṣe iranṣẹ.


Lefi si se àse nla fun u ni ile rẹ̀: ọ̀pọ ijọ awọn agbowode, ati awọn ẹlomiran mbẹ nibẹ̀ ti nwọn ba wọn joko.


Kiyesi i, mo duro li ẹnu ilẹkun, mo si nkànkun, bi ẹnikẹni ba gbọ́ ohùn mi, ti o si ṣí ilẹkun, emi o si wọle tọ̀ ọ wá, emi o si ma ba a jẹun, ati on pẹlu mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan