Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 12:16 - Bibeli Mimọ

16 Nkan wọnyi kò tète yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: ṣugbọn nigbati a ṣe Jesu logo, nigbana ni nwọn ranti pe, a kọwe nkan wọnyi niti rẹ̀, ati pe, on ni nwọn ṣe nkan wọnyi si.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Gbogbo nǹkan wọnyi kò yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní àkókò yìí, ṣugbọn nígbà tí a ti ṣe Jesu lógo, wọ́n ranti pé a ti kọ gbogbo nǹkan wọnyi nípa rẹ̀ ati pé wọ́n ti ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Nǹkan wọ̀nyí kò tètè yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣe Jesu lógo, nígbà náà ni wọ́n rántí pé, a kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ sí i.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 12:16
19 Iomraidhean Croise  

Bẹ̃ni nigbati Oluwa si ti ba wọn sọ̀rọ tan, a si gbà a lọ soke ọrun, o si joko li ọwọ́ ọtún Ọlọrun.


Ṣugbọn ọ̀rọ na kò yé wọn, ẹ̀ru si ba wọn lati bi i lẽre.


Ọkan ninu nkan wọnyi kò si yé wọn: ọ̀rọ yi si pamọ́ fun wọn, bẹ̃ni nwọn ko si mọ̀ ohun ti a wi.


O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti oyé ko yé, ti o si yigbì li àiya lati gbà gbogbo eyi ti awọn woli ti wi gbọ́:


Nigbana li o ṣí wọn ni iyè, ki iwe-mimọ́ ki o le yé wọn,


Ṣugbọn ọ̀rọ na ko yé wọn, o si ṣú wọn li oju, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀ ọ: ẹ̀ru si mba wọn lati bère idi ọ̀rọ na.


Jesu si da wọn lohùn wipe, Wakati na de, ti a o ṣe Ọmọ-enia logo.


Ṣugbọn Olutunu na, Ẹmí Mimọ́, ẹniti Baba yio rán li orukọ mi, on ni yio kọ́ nyin li ohun gbogbo, yio si rán nyin leti ohun gbogbo ti mo ti sọ fun nyin.


Ṣugbọn nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, pe nigbati wakati wọn ba de, ki ẹ le ranti wọn pe mo ti wi fun nyin. Ṣugbọn emi ko sọ nkan wọnyi fun nyin lati ipilẹṣẹ wá, nitoriti mo wà pẹlu nyin.


Njẹ nisisiyi, Baba, ṣe mi logo pẹlu ara rẹ, ogo ti mo ti ní pẹlu rẹ ki aiye ki o to wà.


Nitorina nigbati o jinde kuro ninu okú, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ranti pe, o ti sọ eyi fun wọn; nwọn si gbà iwe-mimọ́ gbọ́, ati ọ̀rọ ti Jesu ti sọ.


(Ṣugbọn o sọ eyi niti Ẹmí, ti awọn ti o gbà a gbọ́ mbọ̀wá gbà: nitori a kò ti ifi Ẹmí Mimọ́ funni; nitoriti a kò ti iṣe Jesu logo.)


Nitorina bi a ti fi ọwọ́ ọtún Ọlọrun gbe e ga, ti o si ti gbà ileri Ẹmí Mimọ́ lati ọdọ Baba, o tú eyi silẹ, ti ẹnyin ri, ti ẹ si gbọ́.


Njẹ ki gbogbo ile Israeli ki o mọ̀ dajudaju pe, Ọlọrun ti fi Jesu na, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, jẹ Oluwa ati Kristi.


Ọlọrun Abrahamu, ati ti Isaaki, ati ti Jakọbu, Ọlọrun awọn baba wa, on li o ti yìn Jesu Ọmọ rẹ̀ logo; ẹniti ẹnyin ti fi le wọn lọwọ, ti ẹnyin si sẹ́ niwaju Pilatu, nigbati o ti pinnu rẹ̀ lati da a silẹ.


Ki a mã wò Jesu olupilẹṣẹ ati alaṣepe igbagbọ́ wa; ẹni, nitori ayọ̀ ti a gbé ká iwaju rẹ̀, ti o farada agbelebu, laika itiju si, ti o si joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ Ọlọrun.


NJẸ pataki ninu ohun ti a nsọ li eyi: Awa ni irú Olori Alufa bẹ̃, ti o joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ ọla nla ninu awọn ọrun:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan