Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 12:1 - Bibeli Mimọ

1 NITORINA nigbati ajọ irekọja kù ijọ mẹfa, Jesu wá si Betani, nibiti Lasaru wà, ẹniti o ti kú, ti Jesu ji dide kuro ninu okú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ mẹfa, Jesu lọ sí Bẹtani níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó kú, tí Jesu jí dìde.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 12:1
13 Iomraidhean Croise  

O si fi wọn silẹ, o jade kuro ni ilu na lọ si Betani; o wọ̀ sibẹ̀.


Jesu si wọ̀ Jerusalemu, ati tẹmpili. Nigbati o si wò ohun gbogbo yiká, alẹ sa ti lẹ tan, o si jade lọ si Betani pẹlu awọn mejila.


O si mu wọn jade lọ titi nwọn fẹrẹ̀ de Betani, nigbati o si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o sure fun wọn.


Si kiyesi i, obinrin kan wà ni ilu na, ẹniti iṣe ẹlẹṣẹ, nigbati o mọ̀ pe Jesu joko njẹun ni ile Farisi, o mu oruba alabastar ororo ikunra wá,


ARA ọkunrin kan si ṣe alaidá, Lasaru, ara Betani, ti iṣe ilu Maria ati Marta arabinrin rẹ̀.


Nigbati o si ti wi bẹ̃ tan, o kigbe li ohùn rara pe, Lasaru, jade wá.


Ẹniti o kú na si jade wá, ti a fi aṣọ okú dì tọwọ tẹsẹ a si fi gèle dì i loju. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ tú u, ẹ si jẹ ki o mã lọ.


Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile: ọ̀pọlọpọ lati igberiko wá si gòke lọ si Jerusalemu ṣiwaju irekọja, lati yà ara wọn si mimọ́.


Ni ijọ keji nigbati ọ̀pọ enia ti o wá si ajọ gbọ́ pe, Jesu mbọ̀ wá si Jerusalemu,


Awọn Hellene kan si wà ninu awọn ti o gòke wá lati sìn nigba ajọ:


Nitorina ijọ enia ninu awọn Ju li o mọ̀ pe o wà nibẹ̀: nwọn si wá, kì iṣe nitori Jesu nikan, ṣugbọn ki nwọn le ri Lasaru pẹlu, ẹniti o ti jí dide kuro ninu okú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan