Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 11:54 - Bibeli Mimọ

54 Nitorina Jesu kò rìn ni gbangba larin awọn Ju mọ́; ṣugbọn o ti ibẹ̀ lọ si igberiko kan ti o sunmọ aginjù, si ilu nla ti à npè ni Efraimu, nibẹ̀ li o si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

54 Nítorí náà, Jesu kò rìn ní gbangba mọ́ láàrin àwọn Juu, ṣugbọn ó kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú kan lẹ́bàá aṣálẹ̀, tí ó ń jẹ́ Efuraimu. Níbẹ̀ ni ó ń gbé pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

54 Nítorí náà Jesu kò rìn ní gbangba láàrín àwọn Júù mọ́; ṣùgbọ́n ó ti ibẹ̀ lọ sí ìgbèríko kan tí ó súnmọ́ aginjù, sí ìlú ńlá kan tí a ń pè ní Efraimu, níbẹ̀ ni ó sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 11:54
9 Iomraidhean Croise  

O si ṣe, lẹhin ọdun meji, Absalomu si ni olurẹrun agutan ni Baal-hasori, eyiti o gbè Efraimu: Absalomu si pe gbogbo awọn ọmọ ọba.


Abijah si lepa Jeroboamu, o si gbà ilu lọwọ rẹ̀, Beteli pẹlu awọn ilu rẹ̀, ati Jeṣana pẹlu awọn ilu rẹ̀, ati Efraimu pẹlu awọn ilu rẹ̀.


O si tún kọja lọ si apakeji Jordani si ibiti Johanu ti kọ́ mbaptisi; nibẹ̀ li o si joko.


Jesu da a lohùn wipe, Emi ti sọ̀rọ ni gbangba fun araiye; nigbagbogbo li emi nkọ́ni ninu sinagogu, ati ni tẹmpili nibiti gbogbo awọn Ju npejọ si: emi kò si sọ ohun kan ni ìkọkọ.


LẸHIN nkan wọnyi Jesu nrìn ni Galili: nitoriti kò fẹ rìn ni Judea, nitori awọn Ju nwá ọ̀na ati pa a.


Ṣugbọn nigbati awọn arakunrin rẹ̀ gòke lọ tan, nigbana li on si gòke lọ si ajọ na pẹlu, kì iṣe ni gbangba, ṣugbọn bi ẹnipe nikọ̀kọ.


Ṣugbọn kò si ẹnikan ti o sọ̀rọ rẹ̀ ni gbangba nitori ìbẹru awọn Ju.


Nitoripe kò si ẹnikẹni ti iṣe ohunkohun nikọ̀kọ, ti on tikararẹ̀ si nfẹ ki a mọ̀ on ni gbangba. Bi iwọ ba nṣe nkan wọnyi, fi ara rẹ hàn fun araiye.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan