Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 11:53 - Bibeli Mimọ

53 Nitorina lati ọjọ na lọ ni nwọn ti jọ gbìmọ pọ̀ lati pa a.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

53 Láti ọjọ́ náà ni wọ́n ti ń gbèrò ọ̀nà tí wọn yóo fi pa Jesu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

53 Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 11:53
22 Iomraidhean Croise  

Nigbati nwọn si ri i lokere; ki o tilẹ to sunmọ eti ọdọ wọn, nwọn di rikiṣi si i lati pa a.


Nigbana ni mo jẹri gbè wọn, mo si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi sùn lẹhin odi, bi ẹnyin ba tun ṣe bẹ̃, emi o fọwọ bà nyin. Lati àkoko na lọ ni nwọn kò si wá lọjọ isimi mọ.


O si ṣe, lati ọjọ na wá, idaji awọn ọmọkunrin mi ṣe iṣẹ na, idaji keji di ọ̀kọ, apata, ati ọrun, ati ihamọra mu; awọn olori si duro lẹhin gbogbo ile Juda.


Ibukún li orukọ Oluwa lati isisiyi lọ ati si i lailai.


Awọn ọba aiye kẹsẹ jọ, ati awọn ijoye ngbimọ pọ̀ si Oluwa ati si Ẹni-ororo rẹ̀ pe,


Nitori ti emi ti ngbọ́ ẹ̀gan ọ̀pọ enia: ẹ̀ru wà niha gbogbo: nigbati nwọn ngbimọ pọ̀ si mi, nwọn gbiro ati gbà ẹmi mi kuro.


Nitori awọn ọta mi nsọ̀rọ si mi; awọn ti nṣọ ọkàn mi si gbimọ̀ pọ̀.


Jeremiah si wi fun Sedekiah pe, Bi emi ba sọ fun ọ, iwọ kì o ha pa mi nitõtọ? bi mo ba si fi imọran fun ọ, iwọ kì yio fetisi ti emi.


Awọn ijoye si sọ fun ọba pe, Jẹ ki a pa ọkunrin yi: nitori bayi li o mu ọwọ awọn ologun ti o kù ni ilu yi rọ, pẹlu ọwọ gbogbo enia, ni sisọ iru ọ̀rọ bayi fun wọn: nitori ọkunrin yi kò wá alafia awọn enia yi, bikoṣe ibi wọn.


Nigbana li awọn Farisi jade lọ, nwọn si gbìmọ nitori rẹ̀, bi awọn iba ti ṣe pa a.


Lati igbana lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ si ifihàn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, bi on ko ti le ṣailọ si Jerusalemu, lati jẹ ọ̀pọ ìya lọwọ awọn àgbagbà ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ki a si pa on, ati ni ijọ kẹta, ki o si jinde.


Kò si si ẹnikan ti o le da a li ohùn ọ̀rọ kan, bẹ̃ni kò si ẹniti o jẹ bi i lẽre ohun kan mọ́ lati ọjọ na lọ.


Nwọn si jọ gbìmọ lati fi ẹ̀tan mu Jesu, ki nwọn si pa a.


Nigbana li olori alufa, ati awọn alàgba, ati gbogbo ajọ igbimọ nwá ẹlẹri eke si Jesu lati pa a;


LẸHIN ọjọ meji ni ajọ irekọja, ati ti aiwukara: ati awọn olori alufa ati awọn akọwe nwá ọ̀na bi nwọn iba ti fi ẹ̀tan mu u, ki nwọn ki o pa a.


Awọn Farisi jade lọ lojukanna lati ba awọn ọmọ-ẹhin Herodu gbìmọ pọ̀ si i, bi awọn iba ti ṣe pa a.


Nigbana li awọn olori alufa ati awọn Farisi pè igbimọ jọ, nwọn si wipe, Kili awa nṣe? nitori ọkunrin yi nṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ àmi.


Ṣugbọn awọn olori alufa gbìmọ ki nwọn le pa Lasaru pẹlu;


LẸHIN nkan wọnyi Jesu nrìn ni Galili: nitoriti kò fẹ rìn ni Judea, nitori awọn Ju nwá ọ̀na ati pa a.


Ṣugbọn nigbati nwọn gbọ́ eyi, àiya wọn gbà ọgbẹ́ de inu, nwọn gbèro ati pa wọn.


Lẹhin igbati ọjọ pipọ kọja, awọn Ju ngbìmọ lati pa a:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan