Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 11:52 - Bibeli Mimọ

52 Ki si iṣe kìki fun orilẹ-ède na nikan, ṣugbọn pẹlu ki o le kó awọn ọmọ Ọlọrun ti a ti fọnka kiri jọ li ọkanṣoṣo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

52 Kì í wá ṣe fún orílẹ̀-èdè wọn nìkan, ṣugbọn kí àwọn ọmọ Ọlọrun tí ó fọ́nká lè papọ̀ di ọ̀kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

52 Kì sì í ṣe kìkì fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn ọmọ Ọlọ́run tí ó fọ́nká kiri, kí ó le kó wọn papọ̀, kí ó sì sọ wọ́n di ọ̀kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 11:52
40 Iomraidhean Croise  

Ọpá-alade ki yio ti ọwọ́ Judah kuro, bẹ̃li olofin ki yio kuro lãrin ẹsẹ̀ rẹ̀, titi Ṣiloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ́ tirẹ̀.


Agbara mi di gbigbẹ bi apãdi: ahọn mi si lẹ̀ mọ́ mi li ẹrẹkẹ; iwọ o mu mi dubulẹ ninu erupẹ ikú.


Gbogbo opin aiye ni yio ranti, nwọn o si yipada si Oluwa: ati gbogbo ibatan orilẹ-ède ni yio wolẹ-sìn niwaju rẹ̀.


Olubukún li orukọ rẹ̀ ti o li ogo titi lai: ki gbogbo aiye ki o si kún fun ogo rẹ̀. Amin, Amin.


Gbe oju rẹ soke yika kiri, si kiyesi i: gbogbo awọn wọnyi ṣà ara wọn jọ, nwọn si wá sọdọ rẹ. Oluwa wipe, Bi mo ti wà, iwọ o fi gbogbo wọn bò ara rẹ, bi ohun ọṣọ́, nitõtọ, iwọ o si há wọn mọ ara, bi iyawo.


O si wipe, O ṣe ohun kekere ki iwọ ṣe iranṣẹ mi, lati gbe awọn ẹyà Jakobu dide, ati lati mu awọn ipamọ Israeli pada: emi o si fi ọ ṣe imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le ṣe igbala mi titi de opin aiye.


Kiyesi i, iwọ o pe orilẹ-ède ti iwọ kò mọ̀, ati orilẹ-ède ti kò mọ̀ ọ yio sare wá sọdọ rẹ, nitori Oluwa Ọlọrun rẹ, ati nitori Ẹni-Mimọ Israeli; nitori on ti ṣe ọ li ogo.


Oluwa Jehofah, ẹniti o ṣà àtanu Israeli jọ wipe, Emi o ṣà awọn ẹlomiran jọ sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn ti a ti ṣà jọ sọdọ rẹ̀.


Gbe oju rẹ soke yika, ki o si wò; gbogbo wọn ṣa ara wọn jọ pọ̀, nwọn wá sọdọ rẹ: awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio ti ọ̀na jíjin wá, a o si tọju awọn ọmọ rẹ obinrin li ẹgbẹ rẹ.


Gẹgẹ bi oluṣọ́ agutan iti iwá ọwọ́-ẹran rẹ̀ ri, li ọjọ ti o wà lãrin awọn agutan rẹ̀ ti o fọnka, bẹ̃li emi o wá agutan mi ri, emi o si gbà wọn nibi gbogbo ti wọn ti fọnka si, li ọjọ kũkũ ati okùnkun biribiri.


Ṣugbọn iye awọn ọmọ Israeli yio ri bi iyanrìn okun, ti a kò le wọ̀n ti a kò si lè ikà; yio si ṣe, ni ibi ti a gbe ti wi fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, ibẹ̀ li a o gbe wi fun wọn pe, Ẹnyin li ọmọ Ọlọrun alãyè.


Tabi obinrin wo li o ni fadaka mẹwa bi o ba sọ ọkan nù, ti kì yio tàn fitilà, ki o si gbá ile, ki o si wá a gidigidi titi yio fi ri i?


Imọlẹ lati mọ́ si awọn Keferi, ati ogo Israeli enia rẹ.


Ṣugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rẹ̀ gbọ́:


Ni ijọ keji Johanu ri Jesu mbọ̀ wá sọdọ rẹ̀; o wipe, Wò o, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kó ẹ̀ṣẹ aiye lọ!


Emi si ní awọn agutan miran, ti kì iṣe ti agbo yi: awọn li emi kò le ṣe alaimu wá pẹlu, nwọn ó si gbọ ohùn mi; nwọn o si jẹ agbo kan, oluṣọ-agutan kan.


Ati emi, bi a ba gbé mi soke kuro li aiye, emi o fà gbogbo enia sọdọ ara mi.


Nitoriti emi wà pẹlu rẹ, kò si si ẹniti yio dide si ọ lati pa ọ lara: nitori mo li enia pupọ ni ilu yi.


Ọlọrun awọn Ju nikan ha ni bi? ki ha ṣe ti awọn Keferi pẹlu? Bẹ̃ni, ti awọn Keferi ni pẹlu:


(Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Mo ti fi ọ ṣe baba orilẹ-ède pupọ,) niwaju ẹniti on gbagbọ́, Ọlọrun tikararẹ̀, ti o sọ okú di ãye, ti o si pè ohun wọnni ti kò si bi ẹnipe nwọn ti wà;


Ẹniti o ti yàn wa tẹlẹ si isọdọmọ nipa Jesu Kristi fun ara rẹ̀, gẹgẹ bi ìdunnú ifẹ rẹ̀:


Gẹgẹ bi ipinnu ataiyebaiye ti o ti pinnu ninu Kristi Jesu Oluwa wa:


JAKỌBU, iranṣẹ Ọlọrun ati ti Jesu Kristi Oluwa, si awọn ẹ̀ya mejila ti o túka kiri, alafia.


PETERU, Aposteli Jesu Kristi, si awọn ayanfẹ ti nṣe atipo ti nwọn tuka kiri si Pontu, Galatia, Kappadokia, Asia, ati Bitinia,


On si ni ètutu fun ẹ̀ṣẹ wa: kì si iṣe fun tiwa nikan, ṣugbọn fun ti gbogbo araiye pẹlu.


Ẹ wo irú ifẹ ti Baba fi fẹ wa, ti a fi npè wa ni ọmọ Ọlọrun; bẹ̃ li a sa jẹ. Nitori eyi li aiye kò ṣe mọ̀ wa, nitoriti ko mọ̀ ọ.


Ninu eyi li awọn ọmọ Ọlọrun nfarahan, ati awọn ọmọ Èṣu: ẹnikẹni ti kò ba nṣe ododo kì iṣe ti Ọlọrun, ati ẹniti kò fẹràn arakunrin rẹ̀.


Olufẹ, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe nisisiyi, a kò si ti ifihàn bi awa ó ti ri: awa mọ pe, nigbati a bá fihan, a ó dabi rẹ̀; nitori awa o ri i ani bi on ti ri.


Nwọn si nkọ orin titun kan, wipe, Iwọ li o yẹ lati gbà iwe na, ati lati ṣí èdidi rẹ̀: nitoriti a ti pa ọ, iwọ si ti fi ẹ̀jẹ rẹ ṣe ìrapada enia si Ọlọrun lati inu ẹyà gbogbo, ati ède gbogbo, ati inu enia gbogbo, ati orilẹ-ède gbogbo wá;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan