Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 11:5 - Bibeli Mimọ

5 Jesu si fẹran Marta, ati arabinrin rẹ̀, ati Lasaru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Jesu fẹ́ràn Mata ati arabinrin rẹ̀ ati Lasaru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 11:5
11 Iomraidhean Croise  

O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, o wọ̀ iletò kan: obinrin kan ti a npè ni Marta si gbà a si ile rẹ̀.


Ṣugbọn Marta nṣe iyọnu ohun pupọ, o si tọ̀ ọ wá, o ni, Oluwa, iwọ kò kuku ṣu si i ti arabinrin mi fi mi silẹ lati mã nikan ṣe aisimi? Wi fun u ki o ràn mi lọwọ.


Ṣugbọn Jesu si dahùn, o si wi fun u pe, Marta, Marta, iwọ nṣe aniyan ati lãlã nitori ohun pipọ:


ARA ọkunrin kan si ṣe alaidá, Lasaru, ara Betani, ti iṣe ilu Maria ati Marta arabinrin rẹ̀.


Nitorina awọn arabinrin rẹ̀ ranṣẹ si i, wipe, Oluwa, wo o, ara ẹniti iwọ fẹran kò da.


Nitorina awọn Ju wipe, sa wo o bi o ti fẹràn rẹ̀ to!


Nitorina nigbati o ti gbọ́ pe, ara rẹ̀ kò da, o gbé ijọ meji si i nibikanna ti o gbé wà.


Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Rabbi, ni lọ̃lọ̃ yi li awọn Ju nwá ọ̀na ati sọ ọ li okuta; iwọ si ntún pada lọ sibẹ̀?


Nitoriti Baba tikararẹ̀ fẹran nyin, nitoriti ẹnyin ti fẹràn mi, ẹ si ti gbagbọ́ pe, lọdọ Ọlọrun li emi ti jade wá.


Mo ti sọ orukọ rẹ di mimọ̀ fun wọn, emi ó si sọ ọ di mimọ̀: ki ifẹ ti iwọ fẹràn mi, le mã wà ninu wọn, ati emi ninu wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan