Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 11:4 - Bibeli Mimọ

4 Nigbati Jesu si gbọ́, o wipe, Aisan yi kì iṣe si ikú, ṣugbọn fun ogo Ọlọrun, ki a le yìn Ọmọ Ọlọrun logo nipasẹ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àìsàn yìí kì í ṣe ti ikú, fún ògo Ọlọrun ni, kí á lè ṣe Ọmọ Ọlọrun lógo nípa rẹ̀ ni.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Nígbà tí Jesu sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún Ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 11:4
20 Iomraidhean Croise  

Ati li owurọ̀ li ẹnyin o si ri ogo OLUWA; nitoriti o gbọ́ kikùn nyin si OLUWA: ta si li awa, ti ẹnyin nkùn si wa?


Ṣugbọn bi emi ba ṣe wọn, bi ẹnyin kò tilẹ gbà mi gbọ́, ẹ gbà iṣẹ na gbọ́: ki ẹnyin ki o le mọ̀, ki o si le ye nyin pe, Baba wà ninu mi, emi si wà ninu rẹ̀.


Jesu wi fun u pe, Emi kò ti wi fun ọ pe, bi iwọ ba gbagbọ́, iwọ o ri ogo Ọlọrun?


Baba, ṣe orukọ rẹ logo. Nitorina ohùn kan ti ọrun wá, wipe, Emi ti ṣe e logo na, emi o si tún ṣe e logo.


NKAN wọnyi ni Jesu sọ, o si gbé oju rẹ̀ soke ọrun, o si wipe, Baba, wakati na de: yìn Ọmọ rẹ logo, ki Ọmọ rẹ ki o le yìn ọ logo pẹlu:


Tirẹ sá ni gbogbo ohun ti iṣe temi, ati temi si ni gbogbo ohun ti iṣe tirẹ; a si ti ṣe mi logo ninu wọn.


Njẹ nisisiyi, Baba, ṣe mi logo pẹlu ara rẹ, ogo ti mo ti ní pẹlu rẹ ki aiye ki o to wà.


Akọṣe iṣẹ àmi yi ni Jesu ṣe ni Kana ti Galili, o si fi ogo rẹ̀ hàn; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbà a gbọ́.


Ki gbogbo enia ki o le mã fi ọlá fun Ọmọ gẹgẹ bi nwọn ti nfi ọlá fun Baba. Ẹniti kò ba fi ọlá fun Ọmọ, kò fi ọlá fun Baba ti o rán a.


Jesu dahùn wipe, Bi mo ba nyìn ara mi li ogo, ogo mi kò jẹ nkan: Baba mi ni ẹniti nyìn mi li ogo, ẹniti ẹnyin wipe, Ọlọrun nyin ni iṣe:


Nitorina nwọn pè ọkunrin afọju na lẹ̃keji, nwọn si wi fun u pe, Fi ogo fun Ọlọrun: awa mọ̀ pe ẹlẹṣẹ li ọkunrin yi iṣe.


Jesu dahùn pe, Kì iṣe nitoriti ọkunrin yi dẹṣẹ, tabi awọn obi rẹ̀: ṣugbọn ki a le fi iṣẹ Ọlọrun hàn lara rẹ̀.


Njẹ mo ni, Nwọn ha kọsẹ̀ ki nwọn ki o le ṣubu? Ki a má ri: ṣugbọn nipa iṣubu wọn, igbala dé ọdọ awọn Keferi, lati mu wọn jowú.


Lẹhin igbati ẹ ti kun fun eso ododo lati ọdọ Jesu Kristi, fun ogo ati iyìn Ọlọrun.


Gẹgẹ bi ìnàgà ati ireti mi pe ki oju ki o máṣe tì mi li ohunkohun, ṣugbọn pẹlu igboiya gbogbo, bi nigbagbogbo, bẹ̃ nisisiyi pẹlu a o gbé Kristi ga lara mi, ibã ṣe nipa ìye, tabi nipa ikú.


Ani ẹnyin ti o ti ipasẹ rẹ̀ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú, ti o si fi ogo fun u; ki igbagbọ́ ati ireti nyin ki o le wà lọdọ Ọlọrun.


Bi ẹnikẹni ba nsọ̀rọ, ki o mã sọ bi ọ̀rọ Ọlọrun; bi ẹnikẹni ba nṣe iṣẹ iranṣẹ, ki o ṣe e bi agbara ti Ọlọrun fifun u: ki a le mã yìn Ọlọrun logo li ohun gbogbo nipa Jesu Kristi, ẹniti ogo ati ìjọba wà fun lai ati lailai. Amin.


Bi a ba ngàn nyin nitori orukọ Kristi, ẹni ibukun ni nyin; nitori Ẹmí ogo ati ti Ọlọrun bà le nyin: nipa tiwọn nwọn nsọ̀rọ rẹ̀ ni ibi, ṣugbọn nipa tinyin a nyìn i logo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan