Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 11:11 - Bibeli Mimọ

11 Nkan wọnyi li o sọ: lẹhin eyini o si wi fun wọn pe, Lasaru ọrẹ́ wa sùn; ṣugbọn emi nlọ ki emi ki o le jí i dide ninu orun rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Lẹ́yìn tí ó ti sọ báyìí tán, ó sọ fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa ti sùn, mò ń lọ jí i.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ: lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 11:11
25 Iomraidhean Croise  

Gehasi si kọja siwaju wọn, o si fi ọpá na le ọmọ na ni iwaju, ṣugbọn kò si ohùn, tabi afiyesi: nitorina o si tun pada lati lọ ipade rẹ̀, o si wi fun u pe, Ọmọ na kò ji.


Iwọ ha kọ́ Ọlọrun wa, ti o ti le awọn ara ilẹ yi jade niwaju Israeli enia rẹ, ti o si fi fun iru-ọmọ Abrahamu, ọrẹ rẹ lailai?


OLUWA si bá Mose sọ̀rọ li ojukoju, bi enia ti ibá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ. O si tun pada lọ si ibudó: ṣugbọn Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, ọdọmọkunrin kan, kò lọ kuro ninu agọ́ na.


Ṣugbọn iwọ, Israeli, ni iranṣẹ mi, Jakobu ẹniti mo ti yàn, iru-ọmọ Abrahamu ọrẹ mi.


Ati ọ̀pọlọpọ ninu awọn ti o sùn ninu erupẹ ilẹ ni yio ji, awọn miran si ìye ainipẹkun, ati awọn miran si itiju ati ẹ̀gan ainipẹkun.


Awọn isà okú si ṣí silẹ; ọ̀pọ okú awọn ẹni mimọ́ ti o ti sùn si jinde,


O wi fun wọn pe, Bìla; nitori ọmọbinrin na ko kú, sisùn li o sùn. Nwọn si fi rín ẹrin ẹlẹyà.


Nigbati o si wọle, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi npariwo, ti ẹ si nsọkun? ọmọ na ko kú, ṣugbọn sisùn li o sùn.


Ṣugbọn bi ẹnikan ba rìn li oru, yio kọsẹ̀, nitoriti kò si imọlẹ ninu rẹ̀.


Nitorina awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Oluwa, bi o ba ṣe pe o sùn, yio sàn.


Ṣugbọn Jesu nsọ ti ikú rẹ̀: ṣugbọn nwọn rò pe, o nsọ ti orun sisun.


Nitorina awọn arabinrin rẹ̀ ranṣẹ si i, wipe, Oluwa, wo o, ara ẹniti iwọ fẹran kò da.


Ẹniti o ba ni iyawo ni ọkọ iyawo; ṣugbọn ọrẹ́ ọkọ iyawo ti o duro ti o si ngbohùn rẹ̀, o nyọ̀ gidigidi nitori ohùn ọkọ iyawo; nitorina ayọ̀ mi yi di kíkun.


O si kunlẹ, o kigbe li ohùn rara pe, Oluwa, má kà ẹ̀ṣẹ yi si wọn li ọrùn. Nigbati o si wi eyi, o sùn.


Njẹ awọn pẹlu ti o sùn ninu Kristi ṣegbé.


Ẹ jí iji ododo, ki ẹ má si dẹṣẹ̀; nitori awọn ẹlomiran kò ni ìmọ Ọlọrun: mo sọ eyi ki oju ki o le ti nyin.


Kiyesi i, ohun ijinlẹ ni mo sọ fun nyin; gbogbo wa kì yio sùn, ṣugbọn gbogbo wa li a o palarada,


Nitorina li o ṣe wipe, Jí, iwọ ẹniti o sùn, si jinde kuro ninu okú, Kristi yio si fun ọ ni imọlẹ.


OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, iwọ o sùn pẹlu awọn baba rẹ; awọn enia yi yio si dide, nwọn o si ma ṣe àgbere tọ̀ awọn oriṣa ilẹ na lẹhin, nibiti nwọn nlọ lati gbé inu wọn, nwọn o si kọ̀ mi silẹ, nwọn o si dà majẹmu mi ti mo bá wọn dá.


Ẹniti o kú fun wa, pe bi a ba jí, tabi bi a ba sùn, ki a le jùmọ wà lãye pẹlu rẹ̀.


Iwe-mimọ́ si ṣẹ ti o wipe, Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u: a si pè e li ọ̀rẹ́ Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan