Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:8 - Bibeli Mimọ

8 Olè ati ọlọṣà ni gbogbo awọn ti o ti wá ṣiwaju mi: ṣugbọn awọn agutan kò gbọ́ ti wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Olè ati ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí wọ́n ti wá ṣiwaju mi. Ṣugbọn àwọn aguntan kò gbọ́ ti wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Olè àti ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi: ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ tiwọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:8
11 Iomraidhean Croise  

EGBE ni fun awọn oluṣọ-agutan, ti nmu agbo-ẹran mi ṣìna, ti o si ntú wọn ka, li Oluwa wi.


Ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn oluṣọ́ agutan Israeli, sọtẹlẹ, ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn oluṣọ́ agutan; pe, Egbé ni fun awọn oluṣọ́ agutan Israeli, ti mbọ́ ara wọn, awọn oluṣọ́ agutan kì ba bọ́ ọwọ́-ẹran?


Awọn olori rẹ̀ ti o wà lãrin rẹ̀ kiniun ti nke ramùramù ni nwọn; awọn onidajọ rẹ̀ ikõkò aṣãlẹ ni nwọn; nwọn kò sán egungun titi di owurọ̀.


Nitori kiye si i, Emi o gbe oluṣọ-agutan kan dide ni ilẹ na, ti kì yio bẹ̀ awọn ti o ṣegbé wò, ti kì yio si wá eyi ti o yapa: ti kì yio ṣe awotan eyi ti o ṣẹ́, tabi kì o bọ́ awọn ti o duro jẹ: ṣugbọn on o jẹ ẹran eyi ti o li ọ̀ra, yio si fà ẽkanna wọn ya pẹrẹpẹ̀rẹ.


LÕTỌ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti kò ba gbà ẹnu-ọ̀na wọ̀ inu agbo agutan, ṣugbọn ti o ba gbà ibomiran gùn oke, on na li olè ati ọlọṣà.


Awọn agutan mi ngbọ ohùn mi, emi si mọ̀ wọn, nwọn a si ma tọ̀ mi lẹhin:


Nwọn kò jẹ tọ̀ alejò lẹhin, ṣugbọn nwọn a ma sá lọdọ rẹ̀: nitoriti nwọn kò mọ̀ ohùn alejò.


Nitori ṣaju ọjọ wọnyi ni Teuda dide, o nwipe ẹni nla kan li on; ẹniti ìwọn irinwo ọkunrin gbatì: ẹniti a pa; ati gbogbo iye awọn ti o gbà tirẹ̀, a tú wọn ká, a si sọ wọn di asan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan