Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:6 - Bibeli Mimọ

6 Owe yi ni Jesu pa fun wọn: ṣugbọn òye ohun ti nkan wọnni jẹ ti o nsọ fun wọn kò yé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Òwe yìí ni Jesu fi bá wọn sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ó ń bá wọn sọ kò yé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Òwe yìí ni Jesu pa fún wọn: ṣùgbọ́n òye ohun tí nǹkan wọ̀nyí tí ó ń sọ fún wọn kò yé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:6
20 Iomraidhean Croise  

Iṣẹ iyanu rẹ kò yé awọn baba wa ni Egipti; nwọn kò ranti ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ; ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si ọ nibi okun, ani nibi Okun pupa.


Nwọn kò mọ̀, bẹ̃ni nwọn kò fẹ ki oye ki o ye wọn; nwọn nrìn li òkunkun; gbogbo ipilẹ aiye yẹ̀ ni ipò wọn.


Oye idajọ kò ye enia buburu: ṣugbọn awọn ti nṣe afẹri Oluwa moye ohun gbogbo.


Nitõtọ ọjẹun aja ni nwọn ti kì iyó, ati oluṣọ́ agutan ti kò moye ni nwọn: olukuluku wọn nwò ọ̀na ara wọn, olukuluku ntọju ere rẹ̀ lati ẹ̀kun rẹ̀ wá.


Ọ̀pọlọpọ li a o wẹ̀ mọ́, nwọn o si di funfun, a o si dan wọn wò: ṣugbọn awọn ẹni-buburu yio ma ṣe buburu: gbogbo awọn enia buburu kì yio kiyesi i; ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n ni yio kiyesi i.


Gbogbo nkan wọnyi ni Jesu fi powe fun awọn ijọ enia; kò si ba wọn sọ̀rọ bikoṣe li owe:


Jesu bi wọn pe, Gbogbo nkan wọnyi yé nyin bi? Nwọn wi fun u pe, Bẹ̃ni, Oluwa.


Ṣugbọn on kì iba wọn sọrọ laìsi owe: nigbati o ba si kù awọn nikan, on a si sọ idi ohun gbogbo fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.


Nkan wọnyi ni mo ti fi owe sọ fun nyin: ṣugbọn akokò de, nigbati emi kì yio fi owe ba nyin sọrọ mọ́, ṣugbọn emi o sọ ti Baba fun nyin gbangba.


Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Wo o, nigbayi ni iwọ nsọ̀rọ̀ gbangba, iwọ kò si sọ ohunkohun li owe.


Nitorina li awọn Ju ṣe mba ara wọn jiyàn, wipe, ọkunrin yi yio ti ṣe le fi ara rẹ̀ fun wa lati jẹ?


Nitorina nigbati ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọ̀rọ ti o le li eyi; tani le gbọ́ ọ?


Ọrọ kili eyi ti o sọ yi, Ẹnyin ó wá mi, ẹ kì yio si ri mi: ati ibiti emi ba wà, ẹnyin kì yio le wá?


Kò yé wọn pe, ti Baba li o nsọ fun wọn.


Ẽtiṣe ti ède mi kò fi yé nyin? nitori ẹ ko le gbọ́ ọ̀rọ mi ni.


Ṣugbọn enia nipa ti ara kò gbà ohun ti Ẹmí Ọlọrun wọnni: nitoripe wère ni nwọn jasi fun u: on kò si le mọ̀ wọn, nitori nipa ti Ẹmí li a fi nwadi wọn.


Owe otitọ nì ṣẹ si wọn lara, Ajá tún pada si ẽbì ara rẹ̀; ati ẹlẹdẹ ti a ti wẹ̀ mọ́ sinu àfọ ninu ẹrẹ̀.


Awa si mọ̀ pe Ọmọ Ọlọrun de, o si ti fi òye fun wa, ki awa ki o le mọ̀ ẹniti iṣe otitọ, awa si mbẹ ninu ẹniti iṣe otitọ, ani ninu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Eyi li Ọlọrun otitọ, ati ìye ainipẹkun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan