42 Awọn enia pipọ nibẹ̀ si gbà a gbọ́.
42 Ọpọlọpọ eniyan bá gbà á gbọ́ níbẹ̀.
42 Àwọn ènìyàn púpọ̀ níbẹ̀ sì gbà á gbọ́.
Nitorina li ọ̀pọ awọn Ju ti o wá sọdọ Maria, ti nwọn ri ohun ti Jesu ṣe, nwọn gbà a gbọ.
Sibẹ ọ̀pọ ninu awọn olori gbà a gbọ́ pẹlu; ṣugbọn nitori awọn Farisi nwọn kò jẹwọ rẹ̀, ki a má bà yọ wọn kuro ninu sinagogu:
Nigbati o si wà ni Jerusalemu, ni ajọ irekọja, lakoko ajọ na, ọ̀pọ enia gbà orukọ rẹ̀ gbọ nigbati nwọn ri iṣẹ àmi rẹ̀ ti o ṣe.
Ọpọ awọn ara Samaria lati ilu na wá si gbà a gbọ́, nitori ọ̀rọ obinrin na, o jẹri pe, O sọ gbogbo ohun ti mo ti ṣe fun mi.
Awọn ọ̀pọlọpọ si i si gbagbọ́ nitori ọ̀rọ rẹ̀;
Ọ̀pọ ninu ijọ enia si gbà a gbọ́, nwọn si wipe, Nigbati Kristi na ba de, yio ha ṣe iṣẹ àmi jù wọnyi lọ, ti ọkunrin yi ti ṣe?
Bi o ti nsọ nkan wọnyi, ọ̀pọ enia gbà a gbọ́.