Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:41 - Bibeli Mimọ

41 Awọn enia pipọ si wá sọdọ rẹ̀, nwọn si wipe, Johanu ko ṣe iṣẹ àmi kan: ṣugbọn otitọ li ohun gbogbo ti Johanu sọ nipa ti ọkunrin yi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

41 Ọpọlọpọ eniyan lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń sọ pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan, ṣugbọn gbogbo ohun tí ó sọ nípa ọkunrin yìí ni ó rí bẹ́ẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

41 Àwọn ènìyàn púpọ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ ààmì kan: Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ohun gbogbo tí Johanu sọ nípa ti ọkùnrin yìí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:41
12 Iomraidhean Croise  

O si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Johanu Baptisti li eyi; o jinde kuro ninu okú; nitorina ni iṣẹ agbara ṣe hàn lara rẹ̀.


Nigbati nwọn si ri i, nwọn wi fun u pe, Gbogbo enia nwá ọ.


O si ṣe, nigbati ainiye ijọ enia pejọ pọ̀, tobẹ̃ ti nwọn ntẹ̀ ara wọn mọlẹ, o tètekọ́ wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ mã ṣọra nyin nitori iwukara awọn Farisi, ti iṣe agabagebe.


O si ṣe, nigbati ijọ enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti o si duro leti adagun Genesareti,


On na li ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, ti o pọju mi lọ, ẹniti emi kò yẹ lati tú okùn bàta rẹ̀.


Akọṣe iṣẹ àmi yi ni Jesu ṣe ni Kana ti Galili, o si fi ogo rẹ̀ hàn; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbà a gbọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan