Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:4 - Bibeli Mimọ

4 Nigbati o si mu awọn agutan tirẹ̀ jade, o ṣiwaju wọn, awọn agutan si ntọ̀ ọ lẹhin: nitoriti nwọn mọ̀ ohùn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Nígbà tí gbogbo àwọn aguntan rẹ̀ bá jáde, a máa lọ níwájú wọn, àwọn aguntan a sì tẹ̀lé e nítorí wọ́n mọ ohùn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Nígbà tí ó bá sì ti mú àwọn àgùntàn tirẹ̀ jáde, yóò síwájú wọn, àwọn àgùntàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn: nítorí tí wọ́n mọ ohùn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:4
23 Iomraidhean Croise  

Ohùn olufẹ mi! sa wò o, o mbọ̀, o nfò lori awọn òke, o mbẹ lori awọn òke kékeké.


Emi sùn, ṣugbọn ọkàn mi ji, ohùn olufẹ mi ni nkànkun, wipe: Ṣilẹkun fun mi, arabinrin mi, olufẹ mi, adaba mi, alailabawọn mi: nitori ori mi kún fun ìri, ati ìdi irun mi fun kikán oru.


Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.


Emi si ní awọn agutan miran, ti kì iṣe ti agbo yi: awọn li emi kò le ṣe alaimu wá pẹlu, nwọn ó si gbọ ohùn mi; nwọn o si jẹ agbo kan, oluṣọ-agutan kan.


Awọn agutan mi ngbọ ohùn mi, emi si mọ̀ wọn, nwọn a si ma tọ̀ mi lẹhin:


On ni oludèna ṣilẹkun fun; awọn agutan si gbọ ohùn rẹ̀: o si pè awọn agutan tirẹ̀ li orukọ, o si ṣe amọ̀na wọn jade.


Nwọn kò jẹ tọ̀ alejò lẹhin, ṣugbọn nwọn a ma sá lọdọ rẹ̀: nitoriti nwọn kò mọ̀ ohùn alejò.


Olè ati ọlọṣà ni gbogbo awọn ti o ti wá ṣiwaju mi: ṣugbọn awọn agutan kò gbọ́ ti wọn.


Bi ẹnikẹni ba nsìn mi, ki o ma tọ̀ mi lẹhin: ati nibiti emi ba wà, nibẹ̀ ni iranṣẹ mi yio wà pẹlu: bi ẹnikẹni ba nsìn mi, on ni Baba yio bù ọlá fun.


Nitori mo ti fi apẹ̃rẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã ṣe gẹgẹ bi mo ti ṣe si nyin.


Nitorina Pilatu wi fun u pe, Njẹ iwọ ha ṣe ọba bi? Jesu dahùn wipe, Iwọ wipe, ọba li emi iṣe. Nitori eyi li a ṣe bí mi, ati nitori idi eyi ni mo si ṣe wá si aiye, ki emi ki o le jẹri si otitọ. Olukuluku ẹniti iṣe ti otitọ ngbọ́ ohùn mi.


Ẹniti o ba ni iyawo ni ọkọ iyawo; ṣugbọn ọrẹ́ ọkọ iyawo ti o duro ti o si ngbohùn rẹ̀, o nyọ̀ gidigidi nitori ohùn ọkọ iyawo; nitorina ayọ̀ mi yi di kíkun.


Ẹ mã ṣe afarawe mi, ani gẹgẹ bi emi ti nṣe afarawe Kristi.


NITORINA ẹ mã ṣe afarawe Ọlọrun bi awọn ọmọ ọ̀wọ́n;


OLUWA Ọlọrun nyin ti nṣaju nyin, on ni yio jà fun nyin, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe fun nyin ni Egipti li oju nyin;


Ki a mã wò Jesu olupilẹṣẹ ati alaṣepe igbagbọ́ wa; ẹni, nitori ayọ̀ ti a gbé ká iwaju rẹ̀, ti o farada agbelebu, laika itiju si, ti o si joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ Ọlọrun.


Nibiti aṣaju wa ti wọ̀ lọ fun wa, ani Jesu, ti a fi jẹ Olori Alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki.


Nitori inu eyi li a pè nyin si: nitori Kristi pẹlu jìya fun nyin, o fi apẹrẹ silẹ fun nyin, ki ẹnyin ki o le mã tọ̀ ipasẹ rẹ̀:


NJẸ bi Kristi ti jìya fun wa nipa ti ara, irú inu kanna ni ki ẹnyin fi hamọra: nitori ẹniti o ba ti jìya nipa ti ara, o ti bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ;


Bẹ̃ni ki iṣe bi ẹniti nlo agbara lori ijọ, ṣugbọn ki ẹ ṣe ara nyin li apẹrẹ fun agbo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan