Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:3 - Bibeli Mimọ

3 On ni oludèna ṣilẹkun fun; awọn agutan si gbọ ohùn rẹ̀: o si pè awọn agutan tirẹ̀ li orukọ, o si ṣe amọ̀na wọn jade.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Òun ni olùṣọ́nà ń ṣí ìlẹ̀kùn fún. Àwọn aguntan a máa gbọ́ ohùn rẹ̀, a sì máa pe àwọn aguntan rẹ̀ ní orúkọ, a máa kó wọn lọ jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Òun ni aṣọ́nà yóò ṣílẹ̀kùn fún; àwọn àgùntàn gbọ́ ohùn rẹ̀: ó sì pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ lórúkọ, ó sì ṣe amọ̀nà wọn jáde.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:3
32 Iomraidhean Croise  

FI eti si ni, Oluṣọ-agutan Israeli, iwọ ti o ndà Josefu bi ọwọ́-agutan; iwọ ti o joko lãrin awọn kerubu tàn imọlẹ jade.


OLUWA si wi fun Mose pe, Emi o ṣe ohun yi ti iwọ sọ pẹlu: nitoriti iwọ ri ore-ọfẹ li oju mi, emi si mọ̀ ọ li orukọ.


Iwọ ma ṣaniyan ati mọ̀ ìwa agbo-ẹran rẹ, ki iwọ ki o si bojuto awọn ọwọ-ẹran rẹ.


Iwọ ti ngbe inu ọgbà, awọn ẹgbẹ rẹ fetisi ohùn rẹ: mu mi gbọ́ ọ pẹlu.


On o bọ́ ọwọ-ẹran rẹ̀ bi oluṣọ-agùtan: yio si fi apá rẹ̀ ko awọn ọdọ-agùtan, yio si kó wọn si aiya rẹ̀, yio si rọra dà awọn ti o loyun.


Emi o si mu awọn afọju bá ọ̀na ti nwọn kò mọ̀ wá; emi o tọ́ wọn ninu ipa ti wọn kò ti mọ̀; emi o sọ okùnkun di imọlẹ niwaju wọn, ati ohun wiwọ́ di titọ. Nkan wọnyi li emi o ṣe fun wọn, emi kì yio si kọ̀ wọn silẹ.


Emi ni oluṣọ-agutan rere, mo si mọ̀ awọn temi, awọn temi si mọ̀ mi.


Emi si ní awọn agutan miran, ti kì iṣe ti agbo yi: awọn li emi kò le ṣe alaimu wá pẹlu, nwọn ó si gbọ ohùn mi; nwọn o si jẹ agbo kan, oluṣọ-agutan kan.


Nigbati o si mu awọn agutan tirẹ̀ jade, o ṣiwaju wọn, awọn agutan si ntọ̀ ọ lẹhin: nitoriti nwọn mọ̀ ohùn rẹ̀.


Emi ni ilẹkun: bi ẹnikan ba ba ọdọ mi wọle, on li a o gbà là, yio wọle, yio si jade, yio si ri koriko.


Ohun gbogbo ti Baba fifun mi, yio tọ̀ mi wá; ẹniti o ba si tọ̀ mi wá, emi kì yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri.


A sá ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, A o si kọ́ gbogbo wọn lati ọdọ Ọlọrun wá. Nitorina ẹnikẹni ti o ba ti gbọ́, ti a si ti ọdọ Baba kọ́, on li o ntọ̀ mi wá.


Awọn ti o si ti yàn tẹlẹ, awọn li o si ti pè: awọn ẹniti o si ti pè, awọn li o si ti dalare: awọn ẹniti o si ti dalare, awọn li o si ti ṣe logo.


Nitoripe ilẹkun nla ati aitase ṣi silẹ fun mi, ọ̀pọlọpọ si li awọn ọtá ti mbẹ.


Mo si bẹ ọ pẹlu, bi alajọru-ajaga mi tõtọ, ran awọn obinrin wọnni lọwọ, nitori nwọn mba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere, ati Klementi pẹlu, ati awọn olubaṣiṣẹ mi iyoku pẹlu, orukọ awọn ti mbẹ ninu iwe ìye.


Ju gbogbo rẹ̀, ẹ mã gbadura fun wa pẹlu, ki Ọlọrun le ṣí ilẹkun fun wa fun ọrọ na, lati mã sọ ohun ijinlẹ Kristi, nitori eyiti mo ṣe wà ninu ìde pẹlu:


Ṣugbọn ipilẹ Ọlọrun ti o daju duro ṣinṣin, o ni èdidi yi wipe, Oluwa mọ̀ awọn ti iṣe tirẹ̀. Ati pẹlu, ki olukuluku ẹniti npè orukọ Oluwa ki o kuro ninu aiṣododo.


Awọn ẹniti a fihàn fun, pe kì iṣe fun awọn tikarawọn, bikoṣe fun awa ni nwọn ṣe iranṣẹ ohun wọnni, ti a ròhin fun nyin nisisiyi, lati ọdọ awọn ti o ti nwãsu ihinrere fun nyin pẹlu Ẹmí Mimọ́ ti a rán lati ọrun wá; ohun ti awọn angẹli nfẹ lati wò.


Ti Ọlọrun li awa: ẹniti o ba mọ̀ Ọlọrun o ngbọ́ ti wa: ẹniti kì ba nṣe ti Ọlọrun kò ngbọ́ ti wa. Nipa eyi li awa mọ̀ ẹmí otitọ, ati ẹmí eke.


Ṣugbọn mo ni ireti lati ri ọ laipẹ, a o si sọrọ li ojukoju.


Bi a ba si ri ẹnikẹni ti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe ìye, a sọ ọ sinu adagun iná.


Kiyesi i, mo duro li ẹnu ilẹkun, mo si nkànkun, bi ẹnikẹni ba gbọ́ ohùn mi, ti o si ṣí ilẹkun, emi o si wọle tọ̀ ọ wá, emi o si ma ba a jẹun, ati on pẹlu mi.


Nitori Ọdọ-Agutan ti mbẹ li arin itẹ́ na ni yio mã ṣe oluṣọ-agutan wọn, ti yio si mã ṣe amọna wọn si ibi orisun omi iyè: Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan