Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:25 - Bibeli Mimọ

25 Jesu da wọn lohùn wipe, Emi ti wi fun nyin, ẹnyin kò si gbagbọ́; iṣẹ ti emi nṣe li orukọ Baba mi, awọn ni njẹri mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

25 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo sọ fun yín, ẹ kò gbàgbọ́. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní orúkọ Baba mi ń jẹ́rìí mi,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:25
17 Iomraidhean Croise  

Jesu da wọn lohùn pe, Ọpọlọpọ iṣẹ rere ni mo fi hàn nyin lati ọdọ Baba mi wá; nitori ewo ninu iṣẹ wọnni li ẹnyin ṣe sọ mi li okuta?


Bi emi kò ba ṣe iṣẹ Baba mi, ẹ máṣe gbà mi gbọ́.


Ṣugbọn bi emi ba ṣe wọn, bi ẹnyin kò tilẹ gbà mi gbọ́, ẹ gbà iṣẹ na gbọ́: ki ẹnyin ki o le mọ̀, ki o si le ye nyin pe, Baba wà ninu mi, emi si wà ninu rẹ̀.


Nigbana li awọn olori alufa ati awọn Farisi pè igbimọ jọ, nwọn si wipe, Kili awa nṣe? nitori ọkunrin yi nṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ àmi.


Ṣugbọn bi o ti ṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ ami to bayi li oju wọn, nwọn kò gbà a gbọ́;


Ẹ gbà mi gbọ́ pe, emi wà ninu Baba, Baba si wà ninu mi: bikoṣe bẹ̃, ẹ gbà mi gbọ́ nitori awọn iṣẹ na pãpã.


Ọpọlọpọ iṣẹ àmi miran ni Jesu ṣe niwaju awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ti a kò kọ sinu iwe yi:


On na li o tọ̀ Jesu wá li oru, o si wi fun u pe, Rabbi, awa mọ̀ pe olukọni lati ọdọ Ọlọrun wá ni iwọ iṣe: nitoripe kò si ẹniti o le ṣe iṣẹ àmi wọnyi ti iwọ nṣe, bikoṣepe Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.


Ọ̀pọ ninu ijọ enia si gbà a gbọ́, nwọn si wipe, Nigbati Kristi na ba de, yio ha ṣe iṣẹ àmi jù wọnyi lọ, ti ọkunrin yi ti ṣe?


Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye.


Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin: nitori bikoṣepé ẹ ba gbagbọ́ pe, emi ni, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin.


Abrahamu baba nyin yọ̀ lati ri ọjọ mi: o si ri i, o si yọ̀.


Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ki Abrahamu to wà, emi ti wà.


Ani Jesu ti Nasareti, bi Ọlọrun ti dà Ẹmi Mimọ́ ati agbara le e lori: ẹniti o nkiri ṣe ore, nṣe didá ara gbogbo awọn ti Èṣu si npọn loju; nitori Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.


Ẹnyin enia Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ wọnyi: Jesu ti Nasareti, ọkunrin ti a fi hàn fun nyin lati ọdọ Ọlọrun wá, nipa iṣẹ agbara ati ti iyanu, ati ti àmi ti Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe lãrin nyin, bi ẹnyin tikaranyin ti mọ̀ pẹlu:


Awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nani irú igbala nla bi eyi; ti àtetekọ bẹ̀rẹ si isọ lati ọdọ Oluwa, ti a si fi mulẹ fun wa lati ọdọ awọn ẹniti o gbọ́;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan