Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:24 - Bibeli Mimọ

24 Nitorina awọn Ju wá duro yi i ká, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ó ti mu wa ṣe iyemeji pẹ to? Bi iwọ ni iṣe Kristi na, wi fun wa gbangba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

24 Àwọn Juu bá pagbo yí i ká, wọ́n sọ fún un pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóo tó fi ọkàn wa balẹ̀? Bí ìwọ bá ni Mesaya, sọ fún wa pàtó.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

24 Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó? Bí ìwọ bá ni Kristi náà, wí fún wa gbangba.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:24
13 Iomraidhean Croise  

Elijah si tọ gbogbo awọn enia na wá, o si wipe, Yio ti pẹ to ti ẹnyin o ma ṣiyemeji? Bi Oluwa ba ni Ọlọrun, ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin: ṣugbọn bi Baali ba ni ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin! Awọn enia na kò si da a li ohùn ọ̀rọ kan.


O si wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a mã reti ẹlomiran?


O si sọ ọ̀rọ na ni gbangba. Peteru si mu u, o bẹ̀rẹ si iba a wi.


Bi awọn enia si ti nreti, ti gbogbo wọn si nrò ninu ara wọn nitori Johanu, bi on ni Kristi bi on kọ́;


Eyi si li ẹrí Johanu, nigbati awọn Ju rán awọn alufã ati awọn ọmọ Lefi lati Jerusalemu wá lati bi i lẽre pe, Tani iwọ ṣe?


Awọn Ju si tún he okuta, lati sọ lù u.


Awọn Ju si da a lohùn, wipe, Awa kò sọ ọ́ li okuta nitori iṣẹ rere, ṣugbọn nitori ọrọ-odi: ati nitori iwọ ti iṣe enia nfi ara rẹ ṣe Ọlọrun.


Nkan wọnyi ni mo ti fi owe sọ fun nyin: ṣugbọn akokò de, nigbati emi kì yio fi owe ba nyin sọrọ mọ́, ṣugbọn emi o sọ ti Baba fun nyin gbangba.


Nitorina nwọn wi fun u pe, Tani iwọ iṣe? Jesu si wi fun wọn pe, Ani eyinì ti mo ti wi fun nyin li àtetekọṣe.


Iwọ ha pọ̀ju Abrahamu baba wa lọ, ẹniti o kú? awọn woli si kú: tani iwọ nfi ara rẹ pè?


Nkan wọnyi li awọn obi rẹ̀ sọ, nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn Ju: nitori awọn Ju ti fi ohùn ṣọkan pe, bi ẹnikan ba jẹwọ pe, Kristi ni iṣe, nwọn ó yọ ọ kuro ninu sinagogu.


Njẹ nitorina bi a ti ni irú ireti bi eyi, awa nfi igboiya pupọ sọ̀rọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan