Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 10:1 - Bibeli Mimọ

1 LÕTỌ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti kò ba gbà ẹnu-ọ̀na wọ̀ inu agbo agutan, ṣugbọn ti o ba gbà ibomiran gùn oke, on na li olè ati ọlọṣà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ àgbàlá ilé tí àwọn aguntan ń sùn sí, ṣugbọn tí ó bá fo ìgànná wọlé, olè ati ọlọ́ṣà ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ inú agbo àgùntàn, ṣùgbọ́n tí ó bá gba ibòmíràn gun òkè, òun náà ni olè àti ọlọ́ṣà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 10:1
28 Iomraidhean Croise  

Nitorina bayi li Oluwa wi niti awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ li orukọ mi, ti emi kò rán; sibẹ nwọn wipe, Idà ati ìyan kì yio wá sori ilẹ yi; nipa idà, pẹlu ìyan, ni awọn woli wọnyi yio ṣegbe.


Emi kò ran awọn woli wọnyi, ṣugbọn nwọn sare: emi kò ba wọn sọ̀rọ, ṣugbọn nwọn sọ asọtẹlẹ.


Sa wò o, emi dojukọ awọn ti o nsọ asọtẹlẹ alá èke, li Oluwa wi, ti nwọn si nrọ́ wọn, ti nwọn si mu enia mi ṣìna nipa eke wọn, ati nipa iran wọn: ṣugbọn emi kò rán wọn, emi kò si paṣẹ fun wọn: nitorina, nwọn kì yio ràn awọn enia yi lọwọ rara, li Oluwa wi.


Nwọn o sure siwa sẹhin ni ilu: nwọn o sure lori odi, nwọn o gùn ori ile; nwọn o gbà oju fèrese wọ̀ inu ile bi olè.


Ẹ mã kiyesi awọn eke woli ti o ntọ̀ nyin wá li awọ agutan, ṣugbọn apanijẹ ikõkò ni nwọn ninu.


Nitorina Jesu tún wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Emi ni ilẹkun awọn agutan.


Jesu dahùn o si wi fun u pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Bikoṣepe a tún enia bí, on kò le ri ijọba Ọlọrun.


Nwọn o ha si ti ṣe wasu, bikoṣepe a rán wọn? gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹsẹ awọn ti nwasu ihinrere alafia ti dara to, awọn ti nwãsu ihin ayọ̀ ohun rere!


Nitori awọn ti o ri bẹ̃ kò sìn Jesu Kristi Oluwa wa, bikoṣe ikùn ara wọn; ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ didùndidùn ni nwọn fi npa awọn ti kò mọ̀ meji li ọkàn dà.


Awọn ẹniti a kò le ṣaipa li ẹnu mọ, nitoriti wọn nda odidi agbo ilé rú, ti nwọn nkọni ni ohun ti kò yẹ nitori ere aitọ́.


Kò si si ẹniti o gbà ọlá yi fun ara rẹ̀, bikoṣe ẹniti a pè lati ọdọ Ọlọrun wá, gẹgẹ bi a ti pè Aaroni.


Igbala ti awọn woli wadi, ti nwọn si wá jinlẹ, awọn ti nwọn sọ asọtẹlẹ ti ore-ọfẹ ti mbọ̀ fun nyin:


ṢUGBỌN awọn woli eke wà lãrin awọn enia na pẹlu, gẹgẹ bi awọn olukọ́ni eke yio ti wà larin nyin, awọn ẹniti yio yọ́ mu adámọ ègbé wọ̀ inu nyin wá, ani ti yio sẹ́ Oluwa ti o rà wọn, nwọn o si mu iparun ti o yara kánkán wá sori ara wọn.


Ati ninu ojukòkoro ni nwọn o mã fi nyin ṣe ere jẹ nipa ọrọ ẹtàn: idajọ ẹniti kò falẹ̀ lati ọjọ ìwa, ìparun wọn kò si tõgbé.


OLUFẸ, ẹ máṣe gbà gbogbo ẹmí gbọ́, ṣugbọn ẹ dán awọn ẹmí wò bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ̀ ti jade lọ sinu aiye.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan