Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:42 - Bibeli Mimọ

42 O si mu u wá sọdọ Jesu. Jesu si wò o, o wipe, Iwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa li a o si ma pè ọ, itumọ̀ eyi ti ijẹ Peteru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

42 Ó bá mú un lọ sọ́dọ̀ Jesu. Jesu tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Johanu; Kefa ni a óo máa pè ọ́.” (Ìtumọ̀ “Kefa” ni “àpáta”, “Peteru” ni ní èdè Giriki.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

42 Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jesu. Jesu sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Peteru).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:42
20 Iomraidhean Croise  

On si wọle, o si sọ fun oluwa rẹ̀ pe, Bayi bayi li ọmọdebinrin ti o ti ilẹ Israeli wá wi.


Orukọ awọn aposteli mejila na ni wọnyi: Eyi ekini ni Simoni, ẹniti a npè ni Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀;


Simoni ẹniti o si sọ apele rẹ̀ ni Peteru;


Nigbati Simoni Peteru si ri i, o wolẹ lẹba ẽkun Jesu, o wipe, Lọ kuro lọdọ mi; nitori ẹlẹṣẹ ni mi, Oluwa.


Simoni, (ẹniti o si sọ ni Peteru,) ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filippi ati Bartolomeu,


Kì iṣe ti gbogbo nyin ni mo nsọ: emi mọ̀ awọn ti mo yàn: ṣugbọn ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, Ẹniti mba mi jẹun pọ̀ si gbé gigĩsẹ rẹ̀ si mi.


Simoni Peteru, ati Tomasi ti a npè ni Didimu, ati Natanaeli ara Kana ti Galili, ati awọn ọmọ Sebede, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji miran jùmọ wà pọ̀.


Jesu wi fun u pe, Lọ ipè ọkọ rẹ, ki o si wá si ihinyi.


Njẹ eyi ni mo wipe, olukuluku nyin nwipe, Emi ni ti Paulu; ati emi ni ti Apollo; ati emi ni ti Kefa; ati emi ni ti Kristi.


Ati pe o farahan Kefa, lẹhin eyini awọn mejila:


Iba ṣe Paulu, tabi Apollo, tabi Kefa, tabi aiye, tabi ìye, tabi ikú, tabi ohun isisiyi, tabi ohun igba ti mbọ̀; tinyin ni gbogbo wọn;


Awa kò ha li agbara lati mã mu aya ti iṣe arabinrin kiri, gẹgẹ bi awọn Aposteli miran, ati bi awọn arakunrin Oluwa, ati Kefa?


Lẹhin ọdún mẹta, nigbana ni mo gòke lọ si Jerusalemu lati lọ kí Peteru, mo si gbé ọdọ rẹ̀ ni ijọ mẹdogun.


Ṣugbọn nigbati Peteru wá si Antioku, mo ta kò o li oju ara rẹ̀, nitoriti o jẹ ẹniti a ba bawi.


Ati nigbati Jakọbu, ati Kefa, ati Johanu, awọn ẹniti o dabi ọwọ̀n, woye ore-ọfẹ ti a fifun mi, nwọn si fi ọwọ́ ọtún ìdapọ fun emi ati Barnaba, pe ki awa ki o mã lọ sọdọ awọn Keferi, ati awọn sọdọ awọn onila.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan