Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:41 - Bibeli Mimọ

41 On tètekọ ri Simoni arakunrin on tikararẹ̀, o si wi fun u pe, Awa ti ri Messia, itumọ̀ eyi ti ijẹ Kristi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

41 Lẹsẹkẹsẹ, Anderu rí Simoni arakunrin rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Àwa ti rí Mesaya!” (Ìtumọ̀ “Mesaya” ni “Kristi.”)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

41 Ohun àkọ́kọ́ tí Anderu ṣe ni láti wá Simoni arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí Messia” (ẹni tí ṣe Kristi).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:41
21 Iomraidhean Croise  

Nigbana ni nwọn wi fun ara wọn pe, Awa kò ṣe rere: oni yi, ọjọ ihinrere ni, awa si dakẹ: bi awa ba duro titi di afẹmọjumọ, iyà yio jẹ wa: njẹ nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a si lọ isọ fun awọn ara ile ọba.


Awọn ọba aiye kẹsẹ jọ, ati awọn ijoye ngbimọ pọ̀ si Oluwa ati si Ẹni-ororo rẹ̀ pe,


Iwọ fẹ ododo, iwọ korira ìwa-buburu: nitori na li Ọlọrun, Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmi ororo ayọ̀ yà ọ ṣolori awọn ọ̀gba rẹ.


Emi ti ri Dafidi, iranṣẹ mi; ororo mi mimọ́ ni mo ta si i li ori:


Ẹmi Oluwa yio si bà le e, ẹmi ọgbọ́n ati oye, ẹmi igbimọ̀ ati agbara, ẹmi imọ̀ran ati ibẹ̀ru Oluwa.


ẸMI Oluwa Jehofah mbẹ lara mi: nitori o ti fi ami ororo yàn mi lati wãsu ihin-rere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi lati ṣe awotán awọn onirobinujẹ ọkàn, lati kede idasilẹ fun awọn igbekùn, ati iṣisilẹ tubu fun awọn ondè.


Kiyesi i, wundia kan yio lóyun, yio si bí ọmọkunrin kan, nwọn o mã pè orukọ rẹ̀ ni Emmanueli, itumọ eyi ti iṣe, Ọlọrun wà pẹlu wa.


Nigbati nwọn si ti ri i, nwọn sọ ohun ti a ti wi fun wọn nipa ti ọmọ yi.


O si wọle li akokò na, o si dupẹ fun Oluwa pẹlu, o si sọ̀rọ rẹ̀ fun gbogbo awọn ti o nreti idande Jerusalemu.


Filippi ri Natanaeli, o si wi fun u pe, Awa ti ri ẹniti Mose ninu ofin ati awọn woli ti kọwe rẹ̀, Jesu ti Nasareti, ọmọ Josefu.


Obinrin na wi fun u pe, Mo mọ̀ pe Messia mbọ̀ wá, ti a npè ni Kristi: nigbati on ba de, yio sọ ohun gbogbo fun wa.


Ani Jesu ti Nasareti, bi Ọlọrun ti dà Ẹmi Mimọ́ ati agbara le e lori: ẹniti o nkiri ṣe ore, nṣe didá ara gbogbo awọn ti Èṣu si npọn loju; nitori Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.


Nitõtọ sá ni, si Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ ti fi oróro yàn, ati Herodu, ati Pontiu Pilatu, pẹlu awọn keferi, ati awọn enia Israeli pejọ si,


Eyiti awa ti ri, ti awa si ti gbọ́ li awa nsọ fun nyin, ki ẹnyin pẹlu ki o le ní ìdapọ pẹlu wa: nitõtọ ìdapọ wa si mbẹ pẹlu Baba, ati pẹlu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan