Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:31 - Bibeli Mimọ

31 Emi kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ki a le fi i hàn fun Israeli, nitorina li emi ṣe wá ti mo nfi omi baptisi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

31 Èmi alára kò mọ̀ ọ́n, ṣugbọn kí á lè fi í han Israẹli ni mo ṣe wá, tí mò ń fi omi ṣe ìwẹ̀mọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

31 Èmi gan an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Israẹli.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:31
15 Iomraidhean Croise  

KIYESI i, Emi o rán onṣẹ mi, yio si tún ọ̀na ṣe niwaju mi: ati Oluwa, ti ẹnyin nwá, yio de li ojijì si tempili rẹ̀, ani onṣẹ majẹmu na, ti inu nyin dùn si; kiye si i, o mbọ̀ wá, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.


Nigbana ni Jesu ti Galili wá si Jordani sọdọ Johanu lati baptisi lọdọ rẹ̀.


A si mbaptisi wọn lọdọ rẹ̀ ni odò Jordani, nwọn njẹwọ ẹ̀ṣẹ wọn.


Ẹmí ati agbara Elijah ni on o si fi ṣaju rẹ̀ lọ, lati pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ti awọn alaigbọran si ọgbọ́n awọn olõtọ; ki o le pèse enia ti a mura silẹ dè Oluwa.


Eyi li ẹniti mo ti wipe, ọkunrin kan mbọ̀ wá lẹhin mi, ẹniti o pọ̀ju mi lọ: nitoriti o ti wà ṣiwaju mi.


Johanu si jẹri, o wipe, mo ri Ẹmi sọkalẹ lati ọrun wá bi àdaba, o si bà le e.


Emi kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ẹniti o rán mi wá, lati fi omi baptisi, on na li o wi fun mi pe, Lori ẹniti iwọ ba ri, ti Ẹmí sọkalẹ si, ti o si bà le e, on na li ẹniti nfi Ẹmí Mimọ́ baptisi.


On na li a si rán fun ẹri, ki o le ṣe ẹlẹri fun imọlẹ na, ki gbogbo enia ki o le gbagbọ́ nipasẹ rẹ̀.


Paulu si wipe, Nitõtọ, ni Johanu fi baptismu ti ironupiwada baptisi, o nwi fun awọn enia pe, ki nwọn ki o gbà ẹniti mbọ̀ lẹhin on gbọ, eyini ni Kristi Jesu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan