Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:27 - Bibeli Mimọ

27 On na li ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, ti o pọju mi lọ, ẹniti emi kò yẹ lati tú okùn bàta rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

27 ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ṣugbọn n kò tó tú okùn bàtà rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

27 Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:27
9 Iomraidhean Croise  

Pe, emi ki yio mu lati fọnran owu titi dé okùn bàta, ati pe, emi kì yio mu ohun kan ti iṣe tirẹ, ki iwọ ki o má ba wipe, Mo sọ Abramu di ọlọrọ̀:


Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin fun ironupiwada: ṣugbọn ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, bàta ẹniti emi ko to gbé; on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin.


O si nwasu, wipe, Ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, okùn bata ẹsẹ ẹniti emi ko to bẹ̀rẹ tú:


Johanu dahùn o si wi fun gbogbo wọn pe, Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin; ṣugbọn ẹniti o lagbarà ju mi lọ mbọ̀, okùn bàta ẹsẹ ẹniti emi ko to itú: on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin:


Johanu si jẹri rẹ̀ o si kigbe, wipe, Eyi ni ẹniti mo sọrọ rẹ̀ pe, Ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, o pọ̀ju mi lọ: nitori o wà ṣiwaju mi.


Eyi li ẹniti mo ti wipe, ọkunrin kan mbọ̀ wá lẹhin mi, ẹniti o pọ̀ju mi lọ: nitoriti o ti wà ṣiwaju mi.


Awọn enia pipọ si wá sọdọ rẹ̀, nwọn si wipe, Johanu ko ṣe iṣẹ àmi kan: ṣugbọn otitọ li ohun gbogbo ti Johanu sọ nipa ti ọkunrin yi.


Bi Johanu si ti nlà ipa tirẹ̀ já, o ni, Tali ẹnyin ṣebi emi iṣe? Emi kì iṣe on. Ṣugbọn ẹ kiyesi i, ẹnikan mbọ̀ lẹhin mi, bata ẹsẹ ẹniti emi kò to itú.


Paulu si wipe, Nitõtọ, ni Johanu fi baptismu ti ironupiwada baptisi, o nwi fun awọn enia pe, ki nwọn ki o gbà ẹniti mbọ̀ lẹhin on gbọ, eyini ni Kristi Jesu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan