Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:21 - Bibeli Mimọ

21 Nwọn si bi i pe, Tani iwọ ha iṣe? Elijah ni ọ bi? O si wipe Bẹ̃kọ. Iwọ ni woli na bi? O si dahùn wipe, Bẹ̃kọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Wọ́n wá bi í pé, “Ta wá ni ọ́? Ṣé Elija ni ọ́ ni?” Ó ní, “Èmi kì í ṣe Elija.” Wọ́n tún bi í pé, “Ìwọ ni wolii tí à ń retí bí?” Ó ní, “Èmi kọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Wọ́n sì bi í léèrè pé, “Ta ha ni ìwọ? Elijah ni ìwọ bí?” Ó sì wí pé, “Èmi kọ́.” “Ìwọ ni wòlíì náà bí?” Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:21
12 Iomraidhean Croise  

Wò o, emi o rán woli Elijah si nyin, ki ọjọ nla-nlà Oluwa, ati ọjọ ti o li ẹ̀ru to de:


Bi ẹnyin o ba gbà a, eyi ni Elijah ti mbọ̀ wá.


Nwọn si wi fun u pe, Omiran ní, Johanu Baptisti; omiran wipe, Elijah; awọn ẹlomiran ni, Jeremiah, tabi ọkan ninu awọn woli.


Ijọ enia si wipe, Eyi ni Jesu wolĩ, lati Nasareti ti Galili.


Ẹmí ati agbara Elijah ni on o si fi ṣaju rẹ̀ lọ, lati pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ti awọn alaigbọran si ọgbọ́n awọn olõtọ; ki o le pèse enia ti a mura silẹ dè Oluwa.


Nitorina nwọn wi fun u pe, Tani iwọ iṣe? ki awa ki o le fi èsi fun awọn ti o rán wa. Kili o wi ni ti ara rẹ?


Nwọn si bi i lẽre, nwọn si wi fun u pe, Njẹ ẽṣe ti iwọ fi mbaptisi, bi iwọ kì ibá ṣe Kristi na, tabi Elijah, tabi woli na?


Nitorina nigbati awọn ọkunrin na ri iṣẹ àmi ti Jesu ṣe, nwọn wipe, Lõtọ eyi ni woli na ti mbọ̀ wá aiye.


Nitorina nigbati ọ̀pọ ninu ijọ enia gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn wipe, Lotọ eyi ni woli na.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan