Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:17 - Bibeli Mimọ

17 Nitoripe nipasẹ Mose li a ti fi ofin funni, ṣugbọn ore-ọfẹ ati otitọ tipasẹ Jesu Kristi wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

17 Nípasẹ̀ Mose ni a ti fún wa ní Òfin, ṣugbọn nípasẹ Jesu Kristi ni oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́ ti wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

17 Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:17
37 Iomraidhean Croise  

Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède aiye: nitori ti iwọ ti gbà ohùn mi gbọ́.


Emi o si fi ọta sãrin iwọ ati obinrin na, ati sãrin irú-ọmọ rẹ ati irú-ọmọ rẹ̀: on o fọ́ ọ li ori, iwọ o si pa a ni gigĩsẹ.


Ãnu ati otitọ padera; ododo ati alafia ti fi ẹnu kò ara wọn li ẹnu.


O ti ranti ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ si awọn ara ile Israeli: gbogbo opin aiye ti ri igbala Ọlọrun wa.


Iwọ o fi otitọ fun Jakobu, ãnu fun Abrahamu, ti iwọ ti bura fun awọn baba wa, lati ọjọ igbani.


Ọ̀rọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ.


Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi.


Nitorina Pilatu wi fun u pe, Njẹ iwọ ha ṣe ọba bi? Jesu dahùn wipe, Iwọ wipe, ọba li emi iṣe. Nitori eyi li a ṣe bí mi, ati nitori idi eyi ni mo si ṣe wá si aiye, ki emi ki o le jẹri si otitọ. Olukuluku ẹniti iṣe ti otitọ ngbọ́ ohùn mi.


Ẹ máṣe rò pe, emi ó fi nyin sùn lọdọ Baba: ẹniti nfi nyin sùn wà, ani Mose, ẹniti ẹnyin gbẹkẹle.


Mose kò ha fi ofin fun yin, kò si ẹnikẹni ninu nyin ti o pa ofin na mọ́? Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá ọ̀na lati pa mi?


Ẹ ó si mọ̀ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira.


Awa mọ̀ pe Ọlọrun ba Mose sọ̀rọ: ṣugbọn bi o ṣe ti eleyi, awa kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá.


Nigbati nwọn dá ọjọ fun u, ọ̀pọlọpọ wọn li o tọ̀ ọ wá ni ile àgbawọ rẹ̀; awọn ẹniti o sọ asọye ọrọ ijọba Ọlọrun fun, o nyi wọn lọkàn pada sipa ti Jesu, lati inu ofin Mose ati awọn woli wá, lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ.


Eyi na li ẹniti o wà ninu ijọ ni ijù pẹlu angẹli na ti o ba a sọ̀rọ li òke Sinai, ati pẹlu awọn baba wa: ẹniti o gbà ọ̀rọ ìye lati fifun wa:


Nitori ẹ̀ṣẹ kì yio ni ipa lori nyin: nitori ẹnyin kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ.


Nitoripe bi o ti wu ki ileri Ọlọrun pọ̀ to, ninu rẹ̀ ni bẹ̃ni: ati ninu rẹ̀ pẹlu ni Amin, si ogo Ọlọrun nipasẹ wa.


Eyi ni mo nwipe, majẹmu ti Ọlọrun ti fi idi rẹ̀ mulẹ niṣãju, ofin ti o de lẹhin ọgbọ̀n-le-nirinwo ọdún kò le sọ ọ di asan, ti a ba fi mu ileri na di alailagbara.


Mose fi ofin kan lelẹ li aṣẹ fun wa, iní ti ijọ enia Jakobu.


Eyi li ofin na ti Mose filelẹ niwaju awọn ọmọ Israeli:


MOSE si pè gbogbo Israeli, o si wi fun wọn pe, Israeli, gbọ́ ìlana ati idajọ ti emi nsọ li etí nyin li oni, ki ẹnyin ki o le kọ́ wọn, ki ẹ si ma pa wọn mọ́, lati ma ṣe wọn.


O si fẹrẹ jẹ́ ohun gbogbo li a fi ẹ̀jẹ wẹ̀nu gẹgẹ bi ofin; ati laisi itajẹsilẹ kò si idariji.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan