Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 1:15 - Bibeli Mimọ

15 Johanu si jẹri rẹ̀ o si kigbe, wipe, Eyi ni ẹniti mo sọrọ rẹ̀ pe, Ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, o pọ̀ju mi lọ: nitori o wà ṣiwaju mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

15 Johanu jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó ń ké rara pé, “Ẹni tí mo sọ nípa rẹ̀ nìyí pé, ‘Ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi tí ó jù mí lọ, nítorí ó ti wà ṣiwaju mi.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

15 Johanu sì jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó kígbe, ó sì wí pé, “Èyí ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ‘Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀jù mí lọ, nítorí òun ti wà ṣáájú mi.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 1:15
21 Iomraidhean Croise  

Oluwa pèse mi ni ipilẹṣẹ ìwa rẹ̀, ṣaju iṣẹ rẹ̀ atijọ.


Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rẹ̀: a o si ma pe orukọ rẹ̀ ni Iyanu, Oludamọ̀ran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, Ọmọ-Alade Alafia.


Ati iwọ Betlehemu Efrata; bi iwọ ti jẹ kekere lãrin awọn ẹgbẹgbẹ̀run Juda, ninu rẹ ni ẹniti yio jẹ olori ni Israeli yio ti jade tọ̀ mi wá; ijade lọ rẹ̀ si jẹ lati igbãni, lati aiyeraiye.


Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin fun ironupiwada: ṣugbọn ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, bàta ẹniti emi ko to gbé; on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin.


O si nwasu, wipe, Ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, okùn bata ẹsẹ ẹniti emi ko to bẹ̀rẹ tú:


Johanu dahùn o si wi fun gbogbo wọn pe, Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin; ṣugbọn ẹniti o lagbarà ju mi lọ mbọ̀, okùn bàta ẹsẹ ẹniti emi ko to itú: on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin:


On na li ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, ti o pọju mi lọ, ẹniti emi kò yẹ lati tú okùn bàta rẹ̀.


Njẹ nisisiyi, Baba, ṣe mi logo pẹlu ara rẹ, ogo ti mo ti ní pẹlu rẹ ki aiye ki o to wà.


Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ki Abrahamu to wà, emi ti wà.


On si wà ṣaju ohun gbogbo, ati ninu rẹ̀ li ohun gbogbo duro ṣọkan.


Jesu Kristi ọkanna ni li aná, ati li oni, ati titi lai.


O nwipe, Emi ni Alfa ati Omega, ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin: ohun ti iwọ ba si ri, kọ ọ sinu iwe, ki o si rán a si awọn ijọ meje; si Efesu, ati si Smirna, ati si Pergamu, ati si Tiatira, ati si Sardi, ati si Filadelfia, ati si Laodikea.


Ati si angẹli ijọ ni Smirna kọwe: Nkan wọnyi li ẹniti iṣe ẹni-iṣaju ati ẹni-ikẹhin wi, ẹniti o ti kú, ti o si tun yè:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan