Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joẹli 3:3 - Bibeli Mimọ

3 Nwọn si ti di ibò fun awọn enia mi; nwọn si ti fi ọmọdekunrin kan fun panṣagà obinrin kan, nwọn si ti tà ọmọdebinrin kan fun ọti-waini, ki nwọn ki o le mu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Wọ́n ti ṣẹ́ gègé lórí àwọn eniyan mi, wọ́n ti ta àwọn ọmọkunrin wọn, wọ́n fi owó wọn san owó aṣẹ́wó, wọ́n sì ta àwọn ọmọbinrin wọn, wọ́n fi owó wọn ra ọtí waini.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Wọ́n si ti di ìbò fún àwọn ènìyàn mi; wọ́n sì ti fi ọmọdékùnrin kan fún panṣágà obìnrin kan, wọ́n sì ta ọmọdébìnrin kan fún ọtí wáìnì, kí wọ́n kí ó lè mu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joẹli 3:3
8 Iomraidhean Croise  

Ani ẹnyin ṣẹ́ gege fun alainibaba, ẹnyin si da iye le ọrẹ nyin.


Jafani, Tubali, ati Meṣeki, awọn li awọn oniṣòwo rẹ: nwọn ti fi ẹrú ati ohun-elò idẹ ṣòwo li ọjà rẹ.


Ji, ẹnyin ọmùti, ẹ si sọkun; si hu, gbogbo ẹnyin ọmùti waini, nitori ọti-waini titun; nitoriti a ké e kuro li ẹnu nyin.


Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Israeli, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn tà olododo fun fàdakà, ati talakà fun bàta ẹsẹ̀ mejeji;


Ni ọjọ ti iwọ duro li apa keji, ni ọjọ ti awọn alejo kó awọn ogun rẹ̀ ni igbèkun lọ, ti awọn ajeji si wọ inu ibode rẹ̀, ti nwọn si ṣẹ keké lori Jerusalemu, ani iwọ wà bi ọkan ninu wọn.


Sibẹ̀sibẹ̀ a kó o lọ, o lọ si oko-ẹrú: awọn ọmọ wẹ́wẹ rẹ̀ li a fi ṣánlẹ̀ pẹlu li ori ita gbogbo; nwọn si di ibò nitori awọn ọlọla rẹ̀ ọkunrin, gbogbo awọn ọlọla rẹ̀ li a si fi ẹwọ̀n dì.


Ati ti kinamoni, ati ti oniruru ohun olõrun didun, ati ti ohun ikunra, ati ti turari, ati ti ọti-waini, ati ti oróro, ati ti iyẹfun daradara, ati ti alikama, ati ti ẹranlá, ati ti agutan, ati ti ẹṣin, ati ti kẹkẹ́, ati ti ẹrú, ati ti ọkàn enìa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan