Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 5:8 - Bibeli Mimọ

8 Nigbati o si gbà iwe na, awọn ẹda alãye mẹrin na, ati awọn àgba mẹrinlelogun na wolẹ niwaju Ọdọ-Agutan na, olukuluku nwọn ní dùru ati ago wura ti o kún fun turari ti iṣe adura awọn enia mimọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Nígbà tí ó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn mẹrinlelogun náà dojúbolẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan yìí. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú hapu kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́, ati àwo wúrà kéékèèké, tí ó kún fún turari. Turari yìí ni adura àwọn eniyan Ọlọrun, àwọn onigbagbọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Nígbà tí ó sì gba ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn mú ohun èlò orin olókùn kan lọ́wọ́, àti ago wúrà tí ó kún fún tùràrí tí i ṣe àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 5:8
27 Iomraidhean Croise  

Jẹ ki adura mi ki o wá si iwaju rẹ bi ẹbọ turari; ati igbé ọwọ mi soke bi ẹbọ aṣãlẹ.


Awọn àgba mẹrinlelogun na a si wolẹ niwaju ẹniti o joko lori itẹ́, nwọn a si tẹriba fun ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai, nwọn a si fi ade wọn lelẹ niwaju itẹ́ na, wipe,


Awọn ẹda alãye mẹrin na wipe; Amin. Awọn àgba mẹrinlelogun na wolẹ, nwọn si foribalẹ fun ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai.


Yi itẹ́ na ká si ni itẹ́ mẹrinlelogun: ati lori awọn itẹ́ na mo ri awọn àgba mẹrinlelogun joko, ti a wọ̀ li aṣọ àlà; ade wura si wà li ori wọn.


Awọn àgba mẹrinlelogun nì, ati awọn ẹda alãye mẹrin nì si wolẹ, nwọn si foribalẹ fun Ọlọrun ti o joko lori itẹ́, wipe, Amin; Halleluiah.


Mo si ri li arin itẹ́ na, ati awọn ẹda alãye mẹrin na, ati li arin awọn àgba na, Ọdọ-Agutan kan duro bi eyiti a ti pa, o ni iwo meje ati oju meje, ti iṣe Ẹmí meje ti Ọlọrun, ti a rán jade lọ si ori ilẹ aiye gbogbo.


Awọn ẹda alaye mẹrin na, ti olukuluku wọn ni iyẹ́ mẹfa, kun fun oju yika ati ninu: nwọn kò si simi li ọsán ati li oru, wipe, Mimọ́, mimọ́, mimọ́, Oluwa Ọlọrun Olodumare, ti o ti wà, ti o si mbẹ, ti o si mbọ̀wá.


Ẹ ma fi duru yìn Oluwa: ẹ ma fi ohun-elo olokùn mẹwa kọrin si i.


Ati ọkan ninu awọn ẹda alãye mẹrin nì fi ìgo wura meje fun awọn angẹli meje na, ti o kún fun ibinu Ọlọrun, ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai.


Mo si ri bi ẹnipe òkun digí ti o dàpọ pẹlu iná: awọn ti o si duro lori okun digi yi jẹ awọn ti nwọn ti ṣẹgun ẹranko na, ati aworan rẹ̀, ati ami rẹ̀ ati iye orukọ rẹ̀, nwọn ni dùru Ọlọrun.


Ki gbogbo enia ki o le mã fi ọlá fun Ọmọ gẹgẹ bi nwọn ti nfi ọlá fun Baba. Ẹniti kò ba fi ọlá fun Ọmọ, kò fi ọlá fun Baba ti o rán a.


Ẹ mu orin mimọ́, ki ẹ si mu ìlu wa, duru didùn pẹlu ohun-elo orin mimọ́.


Nigbana li emi o lọ si ibi pẹpẹ Ọlọrun, sọdọ Ọlọrun ayọ̀ nla mi: nitõtọ, lara duru li emi o ma yìn ọ, Ọlọrun, Ọlọrun mi.


Fi ohùn ipè yìn i: fi ohun-èlo orin ati duru yìn i.


Ati pẹlu, nigbati o mu akọbi ni wá si aiye, o wipe, Ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun ki o foribalẹ fun u.


Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;


Ni ijọ keji Johanu ri Jesu mbọ̀ wá sọdọ rẹ̀; o wipe, Wò o, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kó ẹ̀ṣẹ aiye lọ!


Ati niwaju itẹ́ na si ni okun bi digí, o dabi kristali: li arin itẹ́ na, ati yi itẹ́ na ká, li ẹda alãye mẹrin ti o kún fun oju niwaju ati lẹhin.


Emi si wò, mo si gbọ́ ohùn awọn angẹli pupọ̀ yi itẹ́ na ká, ati yi awọn ẹda alãye na ati awọn àgba na ká: iye wọn si jẹ ẹgbãrun ọna ẹgbãrun ati ẹgbẹgbẹ̀run ọna ẹgbẹgbẹ̀run;


Nwọn nwi li ohùn rara pe, Yiyẹ li Ọdọ-Agutan na ti a ti pa, lati gbà agbara, ati ọrọ̀, ati ọgbọ́n, ati ipá, ati ọlá, ati ogo, ati ibukún.


EMI si ri nigbati Ọdọ-Agutan na ṣí ọ̀kan ninu èdidi wọnni, mo si gbọ́ ọ̀kan ninu awọn ẹda alãye mẹrin nì nwi bi ẹnipe sisan ãrá pe, Wá, wò o.


Gbogbo awọn ti ngbe ori ilẹ aiye yio si mã sin i, olukuluku ẹniti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iyè Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan