Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 4:3 - Bibeli Mimọ

3 Ẹniti o si joko na dabi okuta jaspi ati sardi ni wiwo: oṣumare si ta yi itẹ́ na ká, o dabi okuta smaragdu ni wiwo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ojú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà dàbí òkúta iyebíye oríṣìí meji. Òṣùmàrè yí ìtẹ́ náà ká, ó ń tan ìmọ́lẹ̀ bí òkúta iyebíye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ẹni tí ó sì jókòó náà dàbí òkúta jasperi àti kaneliani lójú. Ni àyíká ìtẹ́ náà ni òṣùmàrè kan wà tí ó dàbí òkúta emeradi lójú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 4:3
13 Iomraidhean Croise  

Nwọn si ri Ọlọrun Israeli; bi iṣẹ okuta Safire wà li abẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, o si dabi irisi ọrun ni imọ́toto rẹ̀.


Ẹsẹ̀ keji, emeraldi, safiru, ati diamondi;


Ati ẹsẹ̀ keji, emeraldi, safiru, ati diamondi.


LI ọdun ti Ussiah ọba kú, emi ri Oluwa joko lori itẹ ti o ga, ti o si gbe ara soke, iṣẹti aṣọ igunwà rẹ̀ kun tempili.


Ati lori ofurufu ti o wà lori wọn, aworan itẹ kan wà, bi irí okuta safire: ati loke aworan itẹ na li aworan kan bi ori enia wà.


Bi irí oṣumare ti o wà ninu awọsanma ni ọjọ ojo, bẹ̃ni irí didan na yika. Eyi ni aworan ogo Oluwa. Nigbati mo si ri, mo dojubolẹ, mo si gbọ́ ohùn ẹnikan ti nsọ̀rọ.


MO si wò, si kiye si i, ninu ofurufu ti o wà loke lori awọn kerubu, ohun kan hàn li ori wọn bi okuta safire bi irí aworan itẹ́.


Iwọ ti wà ni Edeni ọgbà Ọlọrun; oniruru okuta iyebiye ni ibora rẹ, sardiu, topasi, ati diamondi, berili, oniki, ati jasperi, safire, emeraldi, ati karbunkili, ati wura: iṣẹ ìlu rẹ ati ti fère rẹ li a pèse ninu rẹ li ọjọ ti a dá ọ.


MO si ri angẹli miran alagbara o nti ọrun sọkalẹ wá, a fi awọsanma wọ̀ ọ li aṣọ: oṣumare si mbẹ li ori rẹ̀, oju rẹ̀ si dabi õrùn, ati ẹsẹ rẹ̀ bi ọwọ̀n iná:


Ti o ni ogo Ọlọrun: imọlẹ rẹ̀ si dabi okuta iyebiye gidigidi, ani bi okuta jasperi, o mọ́ bi kristali;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan