Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 3:3 - Bibeli Mimọ

3 Nitorina ranti bi iwọ ti gbà, ati bi iwọ ti gbọ́, ki o si pa a mọ, ki o si ronupiwada. Njẹ, bi iwọ kò ba ṣọra, emi o de si ọ bi olè, iwọ kì yio si mọ̀ wakati ti emi o de si ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Nítorí náà, ranti ohun tí o ti gbà tí o sì ti gbọ́, ṣe é, kí o sì ronupiwada. Bí o kò bá jí lójú oorun, n óo dé bí olè, o kò sì ní mọ àkókò tí n óo dé bá ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà. Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 3:3
24 Iomraidhean Croise  

Nibẹ li ẹnyin o ranti ọ̀na nyin, ati gbogbo iṣe nyin, ninu eyiti a ti bà nyin jẹ; ẹ o si sú ara nyin loju ara nyin nitori gbogbo buburu ti ẹnyin ti ṣe.


Nigbana li ẹnyin o ranti ọ̀na buburu nyin, ati iṣe nyin ti kò dara, ẹ o si sú ara nyin li oju ara nyin fun aiṣedẽde nyin, ati fun irira nyin.


Nitorina, ẹ mã ṣọna, bi ẹnyin ko ti mọ̀ ọjọ, tabi wakati tí Ọmọ-enia yio de.


Ẹ mã ṣọra, ki ẹ si mã gbadura: nitori ẹnyin ko mọ̀ igbati akokò na yio de.


Pe, nigbati o ba de li ojijì, ki o máṣe ba nyin li oju orun.


Nitoripe ẹnyin tikaranyin mọ̀ dajudaju pe, ọjọ Oluwa mbọ̀wá gẹgẹ bi olè li oru.


Timotiu, ṣọ ohun ni ti a fi si itọju rẹ, yà kuro ninu ọ̀rọ asan ati ijiyan ohun ti a nfi eke pè ni imọ;


Dì apẹrẹ awọn ọ̀rọ ti o yè koro ti iwọ ti gbọ́ lọdọ mi mu, ninu igbagbọ́ ati ifẹ ti mbẹ ninu Kristi Jesu.


NITORINA o yẹ ti awa iba mã fi iyè gidigidi si ohun wọnni ti awa ti gbọ́, ki a má bã gbá wa lọ kuro ninu wọn nigbakan.


Emi si rò pe o yẹ, niwọn igbati emi ba mbẹ ninu agọ́ yi, lati mã fi iranti rú nyin soke;


OLUFẸ, eyi ni iwe keji ti mo nkọ si nyin; ninu mejeji na li emi nrú inu funfun nyin soke nipa riran nyin leti:


Ṣugbọn ọjọ Oluwa mbọ̀wá bi olè li oru; ninu eyi ti awọn ọrun yio kọja lọ ti awọn ti ariwo nla, ati awọn imọlẹ oju ọrun yio si ti inu oru gbigbona gidigidi di yíyọ, aiye ati awọn iṣẹ ti o wà ninu rẹ̀ yio si jóna lulu.


Kiyesi i, mo mbọ̀ bi olè. Ibukún ni fun ẹniti nṣọna, ti o si npa aṣọ rẹ̀ mọ́, ki o má bã rìn ni ìhoho, nwọn a si ri itiju rẹ̀.


Ṣugbọn eyi ti ẹnyin ni, ẹ di i mu ṣinṣin titi emi o fi de.


Nitorina ranti ibiti iwọ gbé ti ṣubu, ki o si ronupiwada, ki o si ṣe iṣẹ iṣaju; bi kò si ṣe bẹ̃, emi ó si tọ̀ ọ wá, emi o si ṣí ọpá fitila rẹ kuro ni ipò rẹ̀, bikoṣe bi iwọ ba ronupiwada.


Kiyesi i, emi mbọ̀ kánkán: ibukún ni fun ẹniti npa ọ̀rọ isọtẹlẹ inu iwe yi mọ́.


Kiyesi i, emi mbọ̀ nisisiyi: di eyiti iwọ ni mu ṣinṣin, ki ẹnikẹni ki o máṣe gbà ade rẹ.


Gbogbo awọn ti emi ba fẹ ni mo mbawi, ti mo si nnà: nitorina ni itara, ki o si ronupiwada.


Mã ṣọra, ki o si fi ẹsẹ ohun ti o kù mulẹ, ti o ṣe tan lati kú: nitori emi kò ri iṣẹ rẹ ni pipé niwaju Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan