Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 2:3 - Bibeli Mimọ

3 Ti iwọ si farada ìya, ati nitori orukọ mi ti o si fi aiya rán, ti ãrẹ̀ kò si mu ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 O ní ìfaradà. O ti farada ìyà nítorí orúkọ mi, o kò sì jẹ́ kí àárẹ̀ mú ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọ́jú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 2:3
49 Iomraidhean Croise  

Iwọ simi ninu Oluwa, ki o si fi sũru duro dè e; máṣe ikanra nitori ẹniti o nri rere li ọ̀na rẹ̀, nitori ọkunrin na ti o nmu èro buburu ṣẹ.


Nitoripe nitori tirẹ li emi ṣe nrù ẹ̀gan; itiju ti bo mi loju.


Emi o rù ibinu Oluwa, nitori emi ti dẹṣẹ si i, titi yio fi gbà ẹjọ mi rò, ti yio si ṣe idajọ mi; yio mu mi wá si imọlẹ, emi o si ri ododo rẹ̀.


Nwọn si fi agbara mu ọkunrin kan, lati rù agbelebu rẹ̀, Simoni ara Kirene, ẹniti nkọja lọ, ti nti igberiko bọ̀, baba Aleksanderu ati Rufu.


Ẹnikẹni ti kò ba rù agbelebu rẹ̀, ki o si ma tọ̀ mi lẹhin, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi.


O si pa owe kan fun wọn nitori eyiyi pe, o yẹ ki a mã gbadura nigbagbogbo, ki a má si ṣãrẹ̀;


Ninu sũru nyin li ẹnyin o jère ọkàn nyin.


Simoni si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, gbogbo oru aná li awa fi ṣìṣẹ, awa kò si mú nkan: ṣugbọn nitori ọrọ rẹ emi ó jù àwọn na si isalẹ.


Ṣugbọn ti ilẹ rere li awọn, ti nwọn fi ọkàn otitọ ati rere gbọ ọrọ na, nwọn di i mu ṣinṣin, nwọn si fi sũru so eso.


Ṣugbọn gbogbo nkan wọnyi ni nwọn o ṣe si nyin, nitori orukọ mi, nitoriti nwọn kò mọ̀ ẹniti o rán mi.


Ẹ mã yọ̀ ni ireti; ẹ mã mu sũru ninu ipọnju; ẹ mã duro gangan ninu adura;


Ẹ kí Trifena ati Trifosa, awọn ẹniti nṣe lãlã ninu Oluwa. Ẹ kí Persi olufẹ, ti o nṣe lãlã pipọ ninu Oluwa.


Fun awọn ti nfi sũru ni rere-iṣe wá ogo ati ọlá ati aidibajẹ, ìye ainipẹkun;


Ṣugbọn bi awa ba nreti eyi ti awa kò ri, njẹ awa nfi sũru duro dè e.


A mã farada ohun gbogbo, a mã gbà ohun gbogbo gbọ́, a mã reti ohun gbogbo, a mã fàiyarán ohun gbogbo.


Ki ẹnyin ki o tẹriba fun irú awọn bawọnni, ati fun olukuluku olubaṣiṣẹ pọ̀ pẹlu wa ti o si nṣe lãla.


Awa kò ṣogo rekọja ãlà wa, eyini ni lori iṣẹ ẹlomiran; ṣugbọn awa ni ireti pe, bi igbagbọ nyin ti ndagba si i, gẹgẹ bi àla wa awa o di gbigbega lọdọ nyin si i lọpọlọpọ,


Iranṣẹ Kristi ni nwọn bi? (emi nsọ bi aṣiwère) mo ta wọn yọ; niti lãlã lọpọlọpọ, niti paṣan mo rekọja, niti tubu nigbakugba, niti ikú nigbapupọ.


NITORINA bi awa ti ni iṣẹ-iranṣẹ yi, gẹgẹ bi a ti ri ãnu gbà, ãrẹ̀ kò mu wa;


Nitori eyi ni ãrẹ̀ kò ṣe mu wa; ṣugbọn bi ọkunrin ti ode wa ba nparun, sibẹ ọkunrin ti inu wa ndi titun li ojojumọ́.


Nitorina awa ndù u, pe bi awa ba wà ni ile tabi bi a kò si, ki awa ki o le jẹ ẹni itẹwọgbà lọdọ rẹ̀.


Nipa ìnà, ninu tubu, nipa ìrúkerudo, nipa ìṣẹ́, ninu iṣọra, ninu igbawẹ;


Ẹ mã rù ẹrù ọmọnikeji nyin, ki ẹ si fi bẹ̃ mu ofin Kristi ṣẹ.


Ẹ má si jẹ ki agãra da wa ni rere iṣe: nitori awa ó ká nigbati akokò ba de, bi a kò bá ṣe ãrẹ̀.


Ẹ si mã na ọwọ ọ̀rọ ìye jade; ki emi ki o le ṣogo li ọjọ Kristi pe emi kò sáre lasan, bẹni emi kò si ṣe lãlã lasan.


Mo si bẹ ọ pẹlu, bi alajọru-ajaga mi tõtọ, ran awọn obinrin wọnni lọwọ, nitori nwọn mba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere, ati Klementi pẹlu, ati awọn olubaṣiṣẹ mi iyoku pẹlu, orukọ awọn ti mbẹ ninu iwe ìye.


Ki a fi ipá gbogbo sọ nyin di alagbara, gẹgẹ bi agbara ogo rẹ̀, sinu suru ati ipamọra gbogbo pẹlu ayọ̀;


Li aisimi li awa nranti iṣẹ igbagbọ́ nyin ati lãla ifẹ ati sũru ireti nyin ninu Oluwa wa Jesu Kristi, niwaju Ọlọrun ati Baba wa;


Nitori ẹnyin ranti, ará, ìṣẹ́ ati lãlã wa: nitori awa nṣe lãlã li ọsán ati li oru, ki awa ko má bã di ẹrù ru ẹnikẹni ninu nyin, awa wasu ihinrere Ọlọrun fun nyin.


Ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, lati mã mọ awọn ti nṣe lãla larin nyin, ti nwọn si nṣe olori nyin ninu Oluwa, ti nwọn si nkìlọ fun nyin;


Ṣugbọn ẹnyin, ará, ẹ máṣe ṣãrẹ̀ ni rere iṣe.


Ki Oluwa ki o si mã tọ́ ọkan nyin sinu ifẹ Ọlọrun, ati sinu sũru Kristi.


Bẹ̃li awa kò si jẹ onjẹ ẹnikẹni lọfẹ; ṣugbọn ninu ãpọn ati lãlã li a nṣiṣẹ́ lọsan ati loru, ki awa ki o ma bã dẹruba ẹnikẹni ninu nyìn:


Nitori fun eyi li awa nṣe lãlã ti a si njijakadi, nitori awa ni ireti ninu Ọlọrun alãye, ẹniti iṣe Olugbala gbogbo enia, pẹlupẹlu ti awọn ti o gbagbọ́.


Awọn alàgba ti o ṣe akoso daradara ni ki a kà yẹ si ọlá ilọpo meji, pẹlupẹlu awọn ti o ṣe lãlã ni ọ̀rọ ati ni kikọni.


Nitori ẹnyin kò le ṣe alaini sũru, nitori igbati ẹnyin ba ti ṣe ifẹ Ọlọrun tan, ki ẹnyin ki o le gbà ileri na.


NITORINA bi a ti fi awọsanmọ ti o kún to bayi fun awọn ẹlẹri yí wa ká, ẹ jẹ ki a pa ohun idiwọ gbogbo tì si apakan, ati ẹ̀ṣẹ ti o rọrun lati dì mọ wa, ki a si mã fi sũru sure ije ti a gbé ka iwaju wa,


Nitorina ẹ jẹ ki a jade tọ̀ ọ lọ lẹhin ibudo, ki a mã rù ẹ̀gan rẹ̀.


Nitori Ọlọrun kì iṣe alaiṣododo ti yio fi gbagbé iṣẹ nyin ati ifẹ ti ẹnyin fihàn si orukọ rẹ̀, nipa iṣẹ iranṣẹ ti ẹ ti ṣe fun awọn enia mimọ́, ti ẹ si nṣe.


Ki ẹ máṣe di onilọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti nwọn ti ipa igbagbọ́ ati sũru jogún awọn ileri.


Bẹna si ni, lẹhin igbati o fi sũru duro, o ri ileri na gbà.


Ati airekọja kún ìmọ; ati sũru kún airekọja; ati ìwa-bi-Ọlọrun kún sũru;


Emi Johanu, arakunrin nyin ati alabapin pẹlu nyin ninu wahala ati ijọba ati sũru ti mbẹ ninu Jesu, wà ninu erekuṣu ti a npè ni Patmo, nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí Jesu Kristi.


Nitoriti iwọ ti pa ọ̀rọ sũru mi mọ́, emi pẹlu yio pa ọ mọ́ kuro ninu wakati idanwo ti mbọ̀wa de ba gbogbo aiye, lati dán awọn ti ngbe ori ilẹ aiye wo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan