Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Ìfihàn 13:16 - Bibeli Mimọ

16 O si mu gbogbo wọn, ati kekere ati nla, ọlọrọ̀ ati talakà, omnira ati ẹrú, ki a fi àmi kan fun wọn li ọwọ́ ọtún wọn, tabi ni iwaju wọn:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Lẹ́yìn náà, gbogbo eniyan, ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan ńláńlá ati ọlọ́rọ̀ ati talaka, ati ẹrú ati òmìnira ni ẹranko yìí mú kí wọ́n ṣe àmì sí ọwọ́ ọ̀tún tabi iwájú wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti tálákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba ààmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Ìfihàn 13:16
26 Iomraidhean Croise  

Mo si ri awọn ìtẹ́, nwọn si joko lori wọn, a si fi idajọ fun wọn: mo si ri ọkàn awọn ti a ti bẹ́ lori nitori ẹrí Jesu, ati nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati awọn ti kò si foribalẹ fun ẹranko na, ati fun aworan rẹ̀, tabi ti kò si gbà àmi rẹ̀ ni iwaju wọn ati li ọwọ́ wọn; nwọn si wà lãye, nwọn si jọba pẹlu Kristi li ẹgbẹrun ọdún.


A si mu ẹranko na, ati woli eke nì pẹlu rẹ̀, ti o ti nṣe iṣẹ iyanu niwaju rẹ̀, eyiti o ti fi ntàn awọn ti o gbà àmi ẹranko na ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ̀ jẹ. Awọn mejeji yi li a sọ lãye sinu adagun iná ti nfi sulfuru jò.


Wipe, Ẹ máṣe pa aiye, tabi okun, tabi igi lara, titi awa o fi fi èdidi sami si awọn iranṣẹ Ọlọrun wa ni iwaju wọn.


Oluwa si wi fun u pe, La ãrin ilu já, li ãrin Jerusalemu, ki o si sami si iwaju awọn ọkunrin ti nkẹdùn, ti nwọn si nkigbe nitori ohun irira ti nwọn nṣe lãrin rẹ̀.


Ki ẹnyin ki o le jẹ ẹran-ara awọn ọba, ati ẹran-ara awọn olori ogun, ati ẹran-ara awọn enia alagbara, ati ẹran awọn ẹṣin, ati ti awọn ti o joko lori wọn, ati ẹran-ara enia gbogbo, ati ti omnira, ati ti ẹrú, ati ti ewe ati ti àgba.


Ki iwọ ki o si so wọn mọ́ ọwọ́ rẹ fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọja-igbaju niwaju rẹ.


Ẹ fi ọ̀rọ mi wọnyi si àiya nyin ati si ọkàn nyin, ki ẹ si so wọn mọ́ ọwọ́ nyin fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọjá-igbaju niwaju nyin.


Yio si ma ṣe àmi fun ọ li ọwọ́ rẹ, ati fun àmi iranti li agbedemeji oju rẹ, ki ofin OLUWA ki o le wà li ẹnu rẹ: nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú ọ jade kuro ni Egipti.


Ohùn kan si ti ibi itẹ́ na jade wá, wipe, Ẹ mã yìn Ọlọrun wa, ẹnyin iranṣẹ rẹ̀ gbogbo, ẹnyin ti o bẹ̀ru rẹ̀, ati ewe ati àgba.


Mo si ri awọn okú, ati ewe ati àgba, nwọn duro niwaju itẹ; a si ṣi awọn iwe silẹ; a si ṣí awọn iwe miran kan silẹ ti iṣe iwe ìye: a si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe na, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.


Awọn ọba aiye ati awọn ọlọlá ati awọn olori ogun, ati awọn ọlọrọ̀ ati awọn alagbara, ati olukuluku ẹrú, ati olukuluku omnira, si fi ara wọn pamọ́ ninu ihò-ilẹ, ati ninu àpata ori òke:


Ṣugbọn bi mo si ti ri iranlọwọ gbà lọdọ Ọlọrun, mo duro titi o fi di oni, mo njẹri fun ati ewe ati àgba, emi kò sọ ohun miran bikoṣe ohun ti awọn woli ati Mose ti wipe yio ṣẹ:


Yio bùsi i fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ati ewe ati àgba.


Ambọtori fun ẹniti kì iṣojuṣaju awọn ọmọ-alade, tabi ti kò kà ọlọrọ̀ si jù talaka lọ, nitoripe iṣẹ ọwọ rẹ̀ ni gbogbo wọn iṣe.


Mo si ri bi ẹnipe òkun digí ti o dàpọ pẹlu iná: awọn ti o si duro lori okun digi yi jẹ awọn ti nwọn ti ṣẹgun ẹranko na, ati aworan rẹ̀, ati ami rẹ̀ ati iye orukọ rẹ̀, nwọn ni dùru Ọlọrun.


Inu si bi awọn orilẹ-ède, ibinu rẹ si de, ati ìgba lati dá awọn okú lẹjọ, ati lati fi ere fun awọn iranṣẹ rẹ woli ati awọn enia mimọ́ ati awọn ti o bẹ̀ru orukọ rẹ, ati ẹni kekere ati ẹni nla; ati lati run awọn ti npa aiye run.


Nibiti kò le si Hellene ati Ju, ikọla ati aikọla, alaigbede, ara Skitia, ẹrú ati omnira: ṣugbọn Kristi li ohun gbogbo, ninu ohun gbogbo.


Bi ẹnyin ti mọ pe ohun rere kohunrere ti olukuluku ba ṣe, on na ni yio si gbà pada lọdọ Oluwa, ibã ṣe ẹrú, tabi omnira.


Lati isisiyi lọ, ki ẹnikẹni máṣe yọ mi lẹnu mọ́: nitori emi nrù àpá Jesu Oluwa kiri li ara mi.


Kò le si Ju tabi Hellene, ẹrú tabi omnira, ọkunrin tabi obinrin: nitoripe ọ̀kan ni gbogbo nyin jẹ ninu Kristi Jesu.


Nitoripe ninu Ẹmí kan li a ti baptisi gbogbo wa sinu ara kan, iba ṣe Ju, tabi Hellene, iba ṣe ẹrú, tabi omnira; a si ti mú gbogbo wa mu ninu Ẹmí kan.


Ati awọn ọmọ-ẹhin ati awọn ẹni-ọlá, awọn ọlọrọ̀ ati awọn talaka pẹlu.


Pe, ẹnikẹni ti kò ba wá Oluwa Ọlọrun Israeli, pipa li a o pa a, lati ẹni-kekere de ẹni-nla, ati ọkunrin ati obinrin.


Njẹ gẹgẹ bi Janesi ati Jamberi ti kọ oju ija si Mose, bẹ̃li awọn wọnyi kọ oju ija si otitọ: awọn enia ti inu wọn dibajẹ, awọn ẹni ìtanù niti ọran igbagbọ́.


Ẹnikan o si wi fun u pe, Ọgbẹ́ kini wọnyi li ọwọ rẹ? On o si dahùn pe, Wọnyi ni a ti ṣá mi ni ile awọn ọrẹ́ mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan