Ìfihàn 10:3 - Bibeli Mimọ3 O si ke li ohùn rara, bi igbati kiniun ba bú ramuramu: nigbati o si ké, awọn ãrá meje na fọhun. Faic an caibideilYoruba Bible3 Ó wá bú ramúramù bíi kinniun. Nígbà tí ó bú báyìí tán, ààrá meje sán. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní3 Ó sì ké lóhùn rara, bí ìgbà tí kìnnìún bá bú ramúramù. Nígbà tí ó sì ké, àwọn àrá méje náà fọhùn. Faic an caibideil |
Nitori bayi li Oluwa ti wi fun mi pe, Gẹgẹ bi kiniun ati ẹgbọ̀rọ kiniun ti nkùn si ohun-ọdẹ rẹ̀, nigbati a npè ọpọlọpọ oluṣọ́-agutan jade wá si i, ti on kò bẹ̀ru ohùn wọn, ti kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ fun ariwo wọn: bẹ̃li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio sọkalẹ wá lati jà lori okè-nla Sioni, ati lori oke kékèké rẹ̀.