Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Hosea 2:2 - Bibeli Mimọ

2 Ẹ ba iya nyin wijọ, ẹ wijọ; nitori on kì iṣe aya mi, bẹ̃ni emi kì iṣe ọkọ rẹ̀: nitori na jẹ ki on ki o mu gbogbo agberè rẹ̀ kuro ni iwaju rẹ̀, ati gbogbo panṣaga rẹ̀ kuro larin ọyàn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ bá ìyá yín sọ̀rọ̀; nítorí pé kì í ṣe aya mi mọ́, ati pé èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀ mọ́. Ẹ sọ fún un pé kí ó má ṣe àgbèrè mọ́, kí ó sì fi ìṣekúṣe rẹ̀ sílẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Ẹ bá ìyá yín wí, ẹ bá a wí, nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi, Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀. Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀ àti àìṣòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Hosea 2:2
22 Iomraidhean Croise  

On o si gbe ọpagun kan duro fun awọn orilẹ-ède, yio si gbá awọn aṣati Israeli jọ, yio si kó awọn ti a tuka ni Juda jọ lati igun mẹrin aiye wá.


BAYI ni Oluwa wi, Nibo ni iwe ikọsilẹ iyá nyin gbe wà, ẹniti mo ti kọ̀ silẹ? tabi tani ninu awọn onigbese mi ti mo ti tà nyin fun? Kiyesi i, nitori aiṣedẽde nyin li ẹnyin ti tà ara nyin, ati nitori irekọja nyin li a ṣe kọ̀ iyá nyin silẹ.


KE rara, máṣe dasi, gbe ohùn rẹ soke bi ipè, ki o si fi irekọja awọn enia mi hàn wọn, ati ile Jakobu, ẹ̀ṣẹ wọn.


Ki o si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọba Juda, ati olugbe Jerusalemu; Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi: sa wò o, emi o mu ibi wá sihin yi, eyiti eti gbogbo awọn ti o ba gbọ́ ọ, yio ho.


Lọ, ki o si ke li eti Jerusalemu wipe, Bayi li Oluwa wi, Emi ranti rẹ, iṣeun igbà ọmọde rẹ, ifẹ igbeyawo rẹ, nigbati iwọ tẹle mi ni iju, ni ilẹ ti a kì igbin si.


SA wò o, bi a wipe ọkunrin kan kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, ti aya na si kuro lọdọ rẹ̀, ti o si di aya ẹlomiran, ọkunrin na le tun tọ̀ ọ wá? ilẹ na kì yio di ibajẹ gidigidi? ṣugbọn iwọ ti ba ayanfẹ pupọ ṣe panṣaga, iwọ o tun tọ̀ mi wá! li Oluwa wi.


Sa jẹwọ ẹ̀ṣẹ rẹ pe, iwọ ti ṣẹ̀ si Oluwa Ọlọrun rẹ, ati pe, o si tú ọ̀na rẹ ka fun awọn alejo labẹ igi tutu gbogbo, ṣugbọn ẹnyin kò gba ohùn mi gbọ́, li Oluwa wi.


Li ọjọ wọnnì, ile Juda yio rin pẹlu ile Israeli, nwọn o jumọ wá lati ilẹ ariwa, si ilẹ ti emi ti fi fun awọn baba nyin li ogún.


Pẹlupẹlu iwọ ti mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ obinrin, ti iwọ ti bi fun mi, awọn wọnyi ni iwọ si ti fi rubọ si wọn lati jẹ. Ohun kekere ha ni eyi ninu ìwa panṣaga rẹ,


Iwọ ti kọ́ ibi giga rẹ ni gbogbo ikórita, o si ti sọ ẹwà rẹ di ikorira, o si ti ya ẹsẹ rẹ si gbogbo awọn ti nkọja, o si sọ panṣaga rẹ di pupọ.


Iwọ o ha dá wọn lẹjọ bi, ọmọ enia, iwọ o ha da wọn lẹjọ? jẹ ki wọn mọ̀ ohun-irira baba wọn.


Nigbana ni mo wi fun on ti o gbó ni panṣaga, Nwọn o ha bá a ṣe panṣaga nisisiyi, ati on pẹlu wọn?


Ati awọn ọkunrin olododo, nwọn o ṣe idajọ wọn, bi a ti iṣe idajọ awọn àgbere obinrin, ati bi a ti iṣe idajọ awọn obinrin ti o ta ẹjẹ silẹ; nitoripe àgbere ni nwọn, ẹjẹ si wà lọwọ wọn.


Ibẹ̀rẹ ọ̀rọ Oluwa si Hosea. Oluwa si wi fun Hosea, pe, Lọ, fẹ́ agbère obinrin kan fun ara rẹ, ati awọn ọmọ agbère; nitori ilẹ yi ti ṣe agbère gidigidi, kuro lẹhin Oluwa.


Ẹ wi fun awọn arakunrin nyin, Ammi; ati fun awọn arabinrin nyin, Ruhama.


Nitoriti iya wọn ti hùwa agbère: ẹniti o loyun wọn ti ṣe ohun itiju: nitori ti o wipe, Emi o tun tọ̀ awọn ayànfẹ́ mi lẹhìn, ti nfun mi ni onjẹ mi ati omi mi, irun agùtan mi ati ọgbọ̀ mi, ororo mi, ati ohun mimu mi.


Iwọ o si ṣubu li ọ̀san, woli yio si ṣubu pẹlu rẹ li alẹ, emi o si ké iya rẹ kuro.


Ẹniti nfọ́ni ti dide niwaju wọn: nwọn ti fọ́, nwọn kọja lãrin bode, nwọn si ti jade lọ nipa rẹ̀: ọba wọn o si kọja lọ niwaju wọn, Oluwa ni yio si ṣe olori wọn.


Nitorina lati isisiyi lọ awa kò mọ̀ ẹnikan nipa ti ara mọ́; bi awa tilẹ ti mọ̀ Kristi nipa ti ara, ṣugbọn nisisiyi awa kò mọ̀ ọ bẹ̃ mọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan