Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Hosea 2:1 - Bibeli Mimọ

1 Ẹ wi fun awọn arakunrin nyin, Ammi; ati fun awọn arabinrin nyin, Ruhama.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Pe arakunrin rẹ ní “Eniyan mi” kí o sì pe arabinrin rẹ ní “Ẹni tí ó rí àánú gbà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 “Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, ‘Ènìyàn mi,’ kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ ‘àyànfẹ́ mi.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Hosea 2:1
17 Iomraidhean Croise  

Ẹnyin ti kì iṣe enia nigbakan rí, ṣugbọn nisisiyi ẹnyin di enia Ọlọrun, ẹnyin ti kò ti ri ãnu gbà ri, ṣugbọn nisisiyi ẹ ti ri ãnu gbà.


Emi o si gbìn i fun ara mi lori ilẹ, emi o si ṣãnu fun ẹniti kò ti ri ãnu gbà; emi o si wi fun awọn ti kì iṣe enia mi pe, Iwọ li enia mi; on o si wipe, Iwọ li Ọlọrun mi.


Bi mo tilẹ jẹ asọ ọ̀rọ-odì lẹkan rí, ati oninunibini, ati elewu enia: ṣugbọn mo ri ãnu gbà, nitoriti mo ṣe e li aimọ̀ ninu aigbagbọ.


NITORINA bi awa ti ni iṣẹ-iranṣẹ yi, gẹgẹ bi a ti ri ãnu gbà, ãrẹ̀ kò mu wa;


Emi o si mu apá kẹta na là ãrin iná, emi o si yọ́ wọn bi a ti yọ́ fàdakà, emi o si dán wọn wò, bi a ti idán wura wò: nwọn o si pè orukọ mi, emi o si gbọ́ wọn: emi o wipe, Awọn enia mi ni: awọn o si wipe, Oluwa li Ọlọrun mi.


Agọ mi yio wà pẹlu wọn: nitõtọ, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi.


Ẹnyin o si ma gbe ilẹ ti emi fi fun awọn baba nyin; ẹnyin o si ma jẹ enia mi, emi o si ma jẹ Ọlọrun nyin.


Ki wọn le rìn ninu aṣẹ mi, ki wọn si le pa ilana mi mọ, ki nwọn si ṣe wọn: nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn.


Nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn.


Ṣugbọn eyi ni majẹmu ti emi o ba ile Israeli da; Lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi, emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ ọ si aiya wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, awọn o si jẹ enia mi.


Ẹ ba iya nyin wijọ, ẹ wijọ; nitori on kì iṣe aya mi, bẹ̃ni emi kì iṣe ọkọ rẹ̀: nitori na jẹ ki on ki o mu gbogbo agberè rẹ̀ kuro ni iwaju rẹ̀, ati gbogbo panṣaga rẹ̀ kuro larin ọyàn rẹ̀.


Pe ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bíbisi emi o mu irú-ọmọ rẹ bísi i bi irawọ oju-ọrun, ati bi iyanrin eti okun; irú-ọmọ rẹ ni yio si ni ẹnubode awọn ọta wọn;


Nitori Israeli ati Juda, kì iṣe opó niwaju Ọlọrun wọn, niwaju Oluwa, awọn ọmọ-ogun; nitori ilẹ wọn (Babeli) ti kún fun ẹbi si Ẹni-Mimọ Israeli.


Emi o si mu enia ati ẹranko bi si i lori nyin; nwọn o si pọ̀ si i, nwọn o si rẹ̀: emi o si mu nyin joko ni ibugbe nyin, bi ti atijọ, emi o si ṣe si nyin jù igbà ibẹ̀rẹ nyin lọ: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan