Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 9:3 - Bibeli Mimọ

3 Gbogbo ohun alãye, ti nrakò, ni yio ma ṣe onjẹ fun nyin; gẹgẹ bi eweko tutu ni mo fi ohun gbogbo fun nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ni yóo jẹ́ oúnjẹ fún yín, bí mo ti fún yín ní gbogbo ewéko, bẹ́ẹ̀ náà ni mo fún yín ní ohun gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 9:3
18 Iomraidhean Croise  

Ati ìbẹru nyin, ati ìfoya nyin, yio ma wà lara gbogbo ẹranko aiye, ati lara gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun, ati lara gbogbo ohun ti nrakò ni ilẹ, ati lara gbogbo ẹja okun; ọwọ́ nyin li a fi wọn lé.


On kò gbọdọ jẹ ẹran ti o kú fun ara rẹ̀, tabi eyiti ẹranko fàya, lati fi i bà ara rẹ̀ jẹ́: Emi li OLUWA.


Mo mọ̀, o si dá mi loju ninu Jesu Oluwa pe, kò si ohun ti o ṣe aimọ́ fun ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba kà ohunkohun si aimọ́, on li o ṣe aimọ́ fun.


Nitori ijọba Ọlọrun kì iṣe jijẹ ati mimu; bikoṣe ododo, ati alafia, ati ayọ̀ ninu Ẹmí Mimọ́.


Nitori onjẹ máṣe bi iṣẹ Ọlọrun ṣubu. Ohun gbogbo li o mọ́ nitõtọ; ṣugbọn ibi ni fun oluwarẹ̀ na ti o njẹun lọna ikọsẹ.


Ki ẹniti njẹ máṣe kẹgan ẹniti kò jẹ; ki ẹniti kò si jẹ ki o máṣe dá ẹniti njẹ lẹjọ: nitori Ọlọrun ti gbà a.


Ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn ki iṣe ohun gbogbo li o li ere; ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn kì iṣe ohun gbogbo ni igbé-ni-ró.


Nitorina bi ẹnyin ba njẹ, tabi bi ẹnyin ba nmu, tabi ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun.


Ṣugbọn ki iwọ ki o ma pa, ki o si ma jẹ ẹran ninu ibode rẹ gbogbo, ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́, gẹgẹ bi ibukún OLUWA Ọlọrun rẹ ti o fi fun ọ: alaimọ́ ati ẹni mimọ́ ni ki o ma jẹ ninu rẹ̀, bi esuro, ati bi agbọnrin.


Nitorina ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni mã ṣe idajọ nyin niti jijẹ, tabi niti mimu, tabi niti ọjọ ase, tabi oṣù titun, tabi ọjọ isimi:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan