Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 7:1 - Bibeli Mimọ

1 OLUWA si wi fun Noa pe, iwọ wá, ati gbogbo awọn ara ile rẹ sinu ọkọ̀, nitori iwọ ni mo ri li olododo niwaju mi ni iran yi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nígbà tí ó yá OLUWA sọ fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ, nítorí pé ìwọ nìkan ni o jẹ́ olódodo sí mi ní gbogbo ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, nítorí ìwọ nìkan ni mo rí bí olódodo nínú ìran yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 7:1
26 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn iwọ li emi o ba dá majẹmu mi; iwọ o si wọ̀ inu ọkọ̀ na, iwọ ati awọn ọmọ rẹ, ati aya rẹ, ati awọn aya awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ.


Wọnyi ni ìtan Noa: Noa ṣe olõtọ ati ẹniti o pé li ọjọ́ aiye rẹ̀, Noa mba Ọlọrun rìn.


Li ọjọ́ na gan ni Noa wọ̀ inu ọkọ̀, ati Ṣemu, ati Hamu, ati Jafeti, awọn ọmọ Noa, ati aya Noa, (ati awọn aya ọmọ rẹ̀ mẹta pẹlu wọn).


Noa si wọle, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀, ati aya awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, sinu ọkọ̀, nitori kíkun-omi.


Emi si wà ninu iwà-titọ si i, emi si pa ara mi mọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi.


Ẹniti o nrìn dede, o rìn dajudaju: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ayida ọ̀na rẹ̀, on li a o mọ̀.


Ni ibẹ̀ru Oluwa ni igbẹkẹle ti o lagbara: yio si jẹ ibi àbo fun awọn ọmọ rẹ̀.


Orukọ Oluwa, ile-iṣọ agbara ni: Olododo sá wọ inu rẹ̀, o si là.


Bi awọn ọkunrin mẹta wọnyi, Noa, Danieli, ati Jobu tilẹ wà ninu rẹ̀, kiki ẹmi ara wọn ni nwọn o fi ododo wọn gbàla, li Oluwa Ọlọrun wi.


Ẹ wá Oluwa, gbogbo ẹnyin ọlọkàn tutù aiye, ti nṣe idajọ rẹ̀; ẹ wá ododo, ẹ wá ìwa-pẹ̀lẹ: boya a o pa nyin mọ li ọjọ ibinu Oluwa.


Awọn mejeji si ṣe olododo niwaju Ọlọrun, nwọn nrìn ni gbogbo ofin on ìlana Oluwa li ailẹgan.


Bi o si ti ri li ọjọ Noa, bẹ̃ni yio ri li ọjọ Ọmọ-enia.


Nitori fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jìna rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè.


Nipa igbagbọ́ ni Noa, nigbati Ọlọrun kilọ ohun ti koi ti iri fun u, o bẹru Ọlọrun, o si kàn ọkọ̀ fun igbala ile rẹ̀, nipa eyiti o dá aiye lẹbi, o si di ajogún ododo ti iṣe nipa igbagbọ́.


Awọn ti o ṣe alaigbọran nigbakan, nigbati sũru Ọlọrun duro pẹ ni sã kan ni ọjọ Noa, nigbati nwọn fi nkàn ọkọ̀ ninu eyiti à gba ọkàn diẹ là nipa omi, eyini ni ẹni mẹjọ;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan