Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 5:3 - Bibeli Mimọ

3 Adamu si wà li ãdoje ọdún, o si bí ọmọkunrin kan ni jijọ ati li aworan ara rẹ̀; o si pè orukọ rẹ̀ ni Seti:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Nígbà tí Adamu di ẹni aadoje (130) ọdún, ó bí ọmọkunrin kan. Ọmọ náà jọ ọ́ gidigidi, bí Adamu ti rí gan-an ni ọmọ náà rí. Ó bá sọ ọ́ ní Seti.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nígbà tí Adamu di ẹni àádóje ọdún (130), ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Seti.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 5:3
15 Iomraidhean Croise  

Adamu si tun mọ̀ aya rẹ̀, o si bí ọmọkunrin kan, o si pè orukọ rẹ̀ ni Seti: o wipe, nitori Ọlọrun yàn irú-ọmọ miran fun mi ni ipò Abeli ti Kaini pa.


Ati akọ ati abo li o dá wọn; o si súre fun wọn, o si pè orukọ wọn ni Adamu, li ọjọ́ ti a dá wọn.


Ọjọ́ Adamu, lẹhin ti o bí Seti, jẹ ẹgbẹrin ọdún: o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:


Tali o le mu ohun mimọ́ lati inu aimọ́ jade wá? kò si ẹnikan!


Eha ti ṣe ti a o fi da enia lare lọdọ Ọlọrun, tabi ẹniti a bi lati inu obinrin wá yio ha ṣe mọ́?


Kiyesi i, ninu aiṣedede li a gbe bi mi: ati ninu ẹ̀ṣẹ ni iya mi si loyun mi.


Angẹli na si dahùn o si wi fun u pe, Ẹmí Mimọ́ yio tọ̀ ọ wá, ati agbara Ọgá-ogo yio ṣiji bò ọ: nitorina ohun mimọ́ ti a o ti inu rẹ bi, Ọmọ Ọlọrun li a o ma pè e.


Ti iṣe ọmọ Kainani, ti iṣe ọmọ Arfaksadi, ti iṣe ọmọ Semu, ti iṣe ọmọ Noa, ti iṣe ọmọ Lameki,


Eyiti a bí nipa ti ara, ara ni; eyiti a si bí nipa ti Ẹmí, ẹmí ni.


Nitori gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ ti ti ipa ọdọ enia kan wọ̀ aiye, ati ikú nipa ẹ̀ṣẹ; bẹ̃ni ikú si kọja sori enia gbogbo, lati ọdọ ẹniti gbogbo enia ti dẹṣẹ̀:


Gbogbo ẹran-ara kì iṣe ẹran-ara kanna: ṣugbọn ọ̀tọ li ẹran-ara ti enia, ọ̀tọ li ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ ni ti ẹja, ọ̀tọ si ni ti ẹiyẹ.


Bi awa si ti rù aworan ẹni erupẹ̀, bẹ̃li awa ó si ru aworan ẹni ti ọrun.


Ninu awọn ẹniti gbogbo wa pẹlu ti wà rí ninu ifẹkufẹ ara wa, a nmu ifẹ ara ati ti inu ṣẹ; ati nipa ẹda awa si ti jẹ ọmọ ibinu, gẹgẹ bi awọn iyoku pẹlu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan