Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 48:5 - Bibeli Mimọ

5 Njẹ nisisiyi Efraimu ati Manasse, awọn ọmọ rẹ mejeji ti a bí fun ọ ni ilẹ Egipti, ki emi ki o tó tọ̀ ọ wá ni Egipti, ti emi ni nwọn: bi Reubeni on Simeoni, bẹ̃ni nwọn o jẹ́ ti emi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 “Tèmi ni àwọn ọmọkunrin mejeeji tí o bí ní ilẹ̀ Ijipti kí n tó dé, bí Reubẹni ati Simeoni ti jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ náà ni Manase ati Efuraimu jẹ́ tèmi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 “Nítorí náà báyìí, àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí a bí fún ọ ní ilẹ̀ Ejibiti, kí èmi kí ó tó tọ̀ ọ́ wá ní ìhín, ni mo sọ di ọmọ mi fúnra mi. Manase àti Efraimu yóò jẹ́ tèmi gẹ́gẹ́ bí Reubeni àti Simeoni ti jẹ́ tèmi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 48:5
21 Iomraidhean Croise  

Manasse ati Efraimu li a si bí fun Josefu ni ilẹ Egipti, ti Asenati ọmọbinrin Potifera alufa Oni bí fun u.


O SI ṣe lẹhin nkan wọnyi ni ẹnikan wi fun Josefu pe, Kiyesi i, ara baba rẹ kò dá: o si mú awọn ọmọ rẹ̀ mejeji, Manasse ati Efraimu pẹlu rẹ̀.


Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ ti iwọ bí lẹhin wọn ni yio ṣe tirẹ, a o si ma pè wọn li orukọ awọn arakunrin wọn ni ilẹ iní wọn.


Omi ri ọ, Ọlọrun, omi ri ọ, ẹ̀ru bà wọn: nitõtọ ara ibú kò balẹ.


ṢUGBỌN nisisiyi bayi ni Oluwa wi, ẹniti o dá ọ, Jakobu, ati ẹniti o mọ ọ, Israeli, Má bẹru: nitori mo ti rà ọ pada, mo ti pè ọ li orukọ rẹ, ti emi ni iwọ.


Nigbati mo si kọja lọdọ rẹ, ti mo si wò ọ; kiye si i, ìgba rẹ jẹ ìgba ifẹ; mo si nà aṣọ mi bò ọ, mo si bo ihoho rẹ: nitõtọ, mo bura fun ọ, mo si ba ọ da majẹmu, ni Oluwa Ọlọrun wi, iwọ si di temi.


Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; eyi ni yio jẹ ãlà, ti ẹnyin o fi jogún ilẹ na fun ara nyin fun ẹ̀ya mejila Israeli: Josefu yio ni ipin meji.


Ki ẹnyin ki o si jẹ́ mimọ́ fun mi: nitoripe mimọ́ li Emi OLUWA, mo si ti yà nyin sọ̀tọ kuro ninu awọn orilẹ-ède, ki ẹnyin ki o le jẹ́ ti emi.


Nwọn o si jẹ temi ni ini kan, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li ọjọ na ti emi o dá; emi o si dá wọn si gẹgẹ bi enia iti ma dá ọmọ rẹ̀ si ti o nsìn i.


Ti awọn ọmọ Josefu: ti Efraimu; Elliṣama ọmọ Ammihudu: ti Manasse; Gamalieli ọmọ Pedasuru.


Emi o si jẹ Baba fun nyin, ẹnyin o si jẹ ọmọkunrin mi ati ọmọbinrin mi, li Oluwa Olodumare wi.


Ẹniti o ti yàn wa tẹlẹ si isọdọmọ nipa Jesu Kristi fun ara rẹ̀, gẹgẹ bi ìdunnú ifẹ rẹ̀:


Nipa igbagbọ́ ni Jakọbu, nigbati o nkú lọ, o súre fun awọn ọmọ Josefu ni ọ̀kọ̃kan; o si tẹriba, o simi le ori ọpá rẹ̀.


Njẹ nitorina pín ilẹ yi ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya mẹsan, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.


Nitoripe ẹ̀ya meji ni ẹ̀ya awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu: nitorina nwọn kò si fi ipín fun awọn ọmọ Lefi ni ilẹ na, bikoṣe ilu lati ma gbé, pẹlu àgbegbe ilu wọn fun ohunọ̀sin wọn ati ohun-iní wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan