Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 4:2 - Bibeli Mimọ

2 O si bí Abeli arakunrin rẹ̀. Abeli a si ma ṣe oluṣọ-agutan, ṣugbọn Kaini a ma ṣe aroko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkunrin mìíràn, ó sọ ọ́ ní Abeli. Iṣẹ́ darandaran ni Abeli ń ṣe, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Lẹ́yìn náà, ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn tí a pè ní Abeli. Abeli jẹ́ darandaran, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 4:2
19 Iomraidhean Croise  

Nitorina OLUWA Ọlọrun lé e jade kuro ninu ọgbà Edeni, lati ma ro ilẹ ninu eyiti a ti mu u jade wá.


Israeli si wi fun Josefu pe, Ni Ṣekemu ki awọn arakunrin rẹ gbé mbọ́ ẹran? wá, emi o si rán ọ si wọn. On si wi fun u pe, Emi niyi.


ADAMU si mọ̀ Efa aya rẹ̀; o si loyun, o si bí Kaini, o si wipe, Mo ri ọkunrin kan gbà lọwọ OLUWA.


O si ṣe, li opin ọjọ́ wọnni ti Kaini mu ọrẹ ninu eso ilẹ fun OLUWA wá.


Farao si bi awọn arakunrin rẹ̀ pe, Kini iṣẹ nyin? Nwọn si wi fun Farao pe, Oluṣọ-agutan li awọn iranṣẹ rẹ, ati awa, ati awọn baba wa pẹlu.


Noa si bẹ̀rẹ si iṣe àgbẹ, o si gbìn ọgbà-àjara:


Kiyesi i, awọn ọmọ ni ini Oluwa: ọmọ inu si li ère rẹ̀.


MOSE si nṣọ́ agbo-ẹran Jetro baba aya rẹ̀, alufa Midiani: o si dà agbo-ẹran na lọ si apa ẹhin ijù, o si dé Horebu, oke Ọlọrun.


Oluwa si mu mi, bi mo ti ntọ̀ agbo-ẹran lẹhìn, Oluwa si wi fun mi pe, Lọ, sọtẹlẹ̀ fun Israeli enia mi.


Ki a le bère ẹ̀jẹ awọn woli gbogbo, ti a ti ta silẹ lati igba ipilẹṣẹ aiye wá, lọdọ iran yi;


Lati ẹ̀jẹ Abeli wá, titi o si fi de ẹ̀jẹ Sakariah, ti o ṣegbé lãrin pẹpẹ on tẹmpili: lõtọ ni mo wi fun nyin, A o bère rẹ̀ lọdọ iran yi.


Ti eṣu baba nyin li ẹnyin iṣe, ifẹkufẹ baba nyin li ẹ si nfẹ ṣe. Apania li on iṣe lati atetekọṣe, ko si duro ni otitọ; nitoriti kò si otitọ ninu rẹ̀. Nigbati o ba nṣeke, ninu ohun tirẹ̀ li o nsọ, nitori eke ni, ati baba eke.


Ninu eyi li awọn ọmọ Ọlọrun nfarahan, ati awọn ọmọ Èṣu: ẹnikẹni ti kò ba nṣe ododo kì iṣe ti Ọlọrun, ati ẹniti kò fẹràn arakunrin rẹ̀.


Ki iṣe bi Kaini, ti jẹ́ ti ẹni buburu nì, ti o si pa arakunrin rẹ̀. Nitori kili o si ṣe pa a? Nitoriti iṣẹ on jẹ buburu, ti arakunrin rẹ̀ si jẹ ododo.


Ẹnikẹni ti o ba korira arakunrin rẹ̀ apania ni: ẹnyin si mọ̀ pe kò si apania ti o ni ìye ainipẹkun lati mã gbé inu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan