Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 26:3 - Bibeli Mimọ

3 Mã ṣe atipo ni ilẹ yi, emi o si pẹlu rẹ, emi o si bukún u fun ọ; nitori iwọ ati irú-ọmọ rẹ, li emi o fi gbogbo ilẹ wọnyi fun, emi o si mu ara ti mo bú fun Abrahamu, baba rẹ, ṣẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ọlọrun ní, “Máa gbé ilẹ̀ yìí, n óo wà pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ, nítorí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún ní ilẹ̀ wọnyi, n óo sì mú ìlérí mi fún Abrahamu, baba rẹ ṣẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Máa ṣe àtìpó ní ilẹ̀ yìí fún ìgbà díẹ̀, èmi ó sì wà pẹ̀lú rẹ, Èmi yóò sì bùkún fún ọ. Nítorí ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ni èmi yóò fi gbogbo àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí fún, èmi yóò sì fi ìdí ìbúra tí mo ṣe fún Abrahamu baba rẹ múlẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 26:3
42 Iomraidhean Croise  

OLUWA si fi ara hàn fun Abramu, o si wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun: nibẹ̀ li o si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA ti o fi ara hàn a.


Gbogbo ilẹ ti o ri nì, iwọ li emi o sa fi fun ati fun irú-ọmọ rẹ lailai.


Dide, rìn ilẹ na já ni ìna rẹ̀, ati ni ibú rẹ̀; nitori iwọ li emi o fi fun.


Li ọjọ́ na gan li OLUWA bá Abramu dá majẹmu pe, irú-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yi fun, lati odò Egipti wá, titi o fi de odò nla nì, odò Euferate:


Ọlọrun si wipe, Sara, aya rẹ, yio bí ọmọkunrin kan fun ọ nitõtọ; iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Isaaki: emi o fi idi majẹmu mi mulẹ pẹlu rẹ̀, ni majẹmu aiyeraiye, ati pẹlu irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀.


Emi o si fi ilẹ ti iwọ ṣe alejo nibẹ̀ fun ọ, ati fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ, gbogbo ilẹ Kenaani ni iní titi lailai; emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn.


ABRAHAMU si ṣí lati ibẹ̀ lọ si ilẹ ìha gusù, o si joko li agbedemeji Kadeṣi on Ṣuri; o si ṣe atipo ni Gerari.


O si ṣe lẹhin ikú Abrahamu li Ọlọrun bukún fun Isaaki, ọmọ rẹ̀; Isaaki si joko leti kanga Lahai-roi.


Nigbana ni Isaaki funrugbìn ni ilẹ na, o si ri ọrọrún mu li ọdún na; OLUWA si busi i fun u:


Nitori ti o ni agbo-agutan, ati ini agbo-ẹran nla ati ọ̀pọlọpọ ọmọ-ọdọ: awọn ara Filistia si ṣe ilara rẹ̀.


OLUWA si farahàn a li oru ọjọ́ na, o si wipe, Emi li Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ: máṣe bẹ̀ru, nitori ti emi wà pẹlu rẹ, emi o si busi i fun ọ, emi o si mu irú-ọmọ rẹ rẹ̀, nitori Abrahamu ọmọ-ọdọ mi.


Si kiyesi i, OLUWA duro loke rẹ̀, o si wi pe, Emi li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu baba rẹ, ati Ọlọrun Isaaki; ilẹ ti iwọ dubulẹ le nì, iwọ li emi o fi fun, ati fun irú-ọmọ rẹ.


Si kiyesi i, emi wà pẹlu rẹ, emi o sì pa ọ mọ́ ni ibi gbogbo ti iwọ nlọ, emi o si tun mu ọ bọ̀wá si ilẹ yi; nitori emi ki yio kọ̀ ọ silẹ, titi emi o fi ṣe eyiti mo wi fun ọ tan.


OLUWA si wi fun Jakobu pe, Pada lọ si ilẹ awọn baba rẹ, ati si ọdọ awọn ara rẹ; emi o si pẹlu rẹ.


Ati ilẹ ti mo ti fi fun Abrahamu ati Isaaki, iwọ li emi o fi fun, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ li emi o fi ilẹ na fun.


OLUWA si wà pẹlu Josefu, o si ṣe alasiki enia; o si wà ni ile oluwa rẹ̀ ara Egipti na.


Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josefu, o si ṣãnu fun u, o si fun u li ojurere li oju onitúbu.


Israeli si wi fun Josefu pe, Wò o, emi kú: ṣugbọn Ọlọrun yio wà pẹlu nyin, yio si tun mú nyin lọ si ilẹ awọn baba nyin.


Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi kú: Ọlọrun yio si bẹ̀ nyin wò nitõtọ, yio si mú nyin jade kuro ni ilẹ yi, si ilẹ ti o ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu.


Majẹmu ti o ba Abrahamu da, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki;


O ti ranti majẹmu rẹ̀ lailai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran.


Majẹmu ti o ba Abrahamu dá, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki;


Emi o fi ẹsẹ̀ rẹ le ọ̀na, emi o si kọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ o rìn: emi o ma fi oju mi tọ́ ọ.


Oluwa, gbọ́ adura mi, ki o si fi eti si ẹkún mi, ki o máṣe pa ẹnu rẹ mọ́ si omije mi: nitori alejo li emi lọdọ rẹ, ati atipo, bi gbogbo awọn baba mi ti ri.


Ọlọrun si gbọ́ irora wọn, Ọlọrun si ranti majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, pẹlu Isaaki, ati pẹlu Jakobu.


O si wipe, Nitõtọ emi o wà pẹlu rẹ; eyi ni yio si ṣe àmi fun ọ pe, emi li o rán ọ: nigbati iwọ ba mú awọn enia na lati Egipti jade wá, ẹnyin o sìn Ọlọrun lori oke yi.


Emi si ti bá wọn da majẹmu mi pẹlu, lati fun wọn ni ilẹ Kenaani, ilẹ atipo wọn, nibiti nwọn gbé ṣe atipo.


Emi o si gbà nyin ṣe enia fun ara mi, emi o si jẹ́ Ọlọrun fun nyin: ẹnyin o si mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti.


Emi o si mú nyin lọ sinu ilẹ na, ti mo ti bura lati fi fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu; emi o si fi i fun nyin ni iní: Emi li OLUWA.


Nigbati iwọ ba nlà omi kọja, emi o pẹlu rẹ; ati lãrin odò, nwọn ki yio bò ọ mọlẹ: nigbati iwọ ba nrìn ninu iná, ki yio jo ọ, bẹ̃ni ọwọ́-iná ki yio ràn ọ.


Má bẹ̀ru: nitori emi wà pẹlu rẹ; emi o mu iru-ọmọ rẹ lati ìla-õrun wá, emi o si ṣà ọ jọ lati ìwọ-õrun wá.


Iwọ o fi otitọ fun Jakobu, ãnu fun Abrahamu, ti iwọ ti bura fun awọn baba wa, lati ọjọ igbani.


Ọlọrun ki iṣe enia ti yio fi ṣeké; bẹ̃ni ki iṣe ọmọ enia ti yio fi ronupiwada: a ma wi, ki o má si ṣe bi? tabi a ma sọ̀rọ ki o má mu u ṣẹ?


Wò o, mo ti fi ilẹ na siwaju nyin: ẹ wọ̀ ọ lọ ki ẹ si gbà ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba nyin, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fi fun wọn ati fun irú-ọmọ wọn lẹhin wọn.


OLUWA si wi fun u pe, Eyi ni ilẹ ti mo bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, wipe, Emi o fi i fun irú-ọmọ rẹ: emi mu ọ fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ ki yio rekọja lọ sibẹ̀.


Nkan wọnni, ti ẹnyin ti kọ́, ti ẹnyin si ti gbà, ti ẹnyin si ti gbọ́, ti ẹnyin si ti ri lọwọ mi, ẹ mã ṣe wọn: Ọlọrun alafia yio si wà pẹlu nyin.


Nipa igbagbọ́ li o ṣe atipo ni ilẹ ileri, bi ẹnipe ni ilẹ àjeji, o ngbé inu agọ́, pẹlu Isaaki ati Jakọbu, awọn ajogún ileri kanna pẹlu rẹ̀:


Ninu eyiti bi Ọlọrun ti nfẹ gidigidi lati fi aileyipada ìmọ rẹ̀ han fun awọn ajogún ileri, o fi ibura sãrin wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan