Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Gẹnẹsisi 21:3 - Bibeli Mimọ

3 Abrahamu si pè orukọ ọmọ rẹ̀ ti a bí fun u, ni Isaaki, ẹniti Sara bí fun u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Abrahamu sọ ọmọkunrin náà ní Isaaki.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Abrahamu sì sọ orúkọ ọmọ náà tí Sara bí fun un ní Isaaki.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Gẹnẹsisi 21:3
11 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun si wipe, Sara, aya rẹ, yio bí ọmọkunrin kan fun ọ nitõtọ; iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Isaaki: emi o fi idi majẹmu mi mulẹ pẹlu rẹ̀, ni majẹmu aiyeraiye, ati pẹlu irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀.


Ṣugbọn majẹmu mi li emi o ba Isaaki dá, ẹniti Sara yio bí fun ọ li akoko iwoyi amọ́dun.


Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Máṣe jẹ ki o buru li oju rẹ nitori ọmọdekunrin na, ati nitori ẹrubirin rẹ; ni gbogbo eyiti Sara sọ fun ọ, fetisi ohùn rẹ̀; nitori ninu Isaaki li a o ti pè irú-ọmọ rẹ.


Sara si wipe, Ọlọrun pa mi lẹrin; gbogbo ẹniti o gbọ́ yio si rẹrin pẹlu mi.


O si wi fun u pe, Mu ọmọ rẹ nisisiyi, Isaaki, ọmọ rẹ na kanṣoṣo, ti iwọ fẹ́, ki iwọ ki o si lọ si ilẹ Moria; ki o si fi i rubọ sisun nibẹ̀ lori ọkan ninu oke ti emi o sọ fun ọ.


Iwọnyi si ni iran Isaaki, ọmọ Abrahamu: Abrahamu bí Isaaki:


Abrahamu bí Isaaki; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bí Juda ati awọn arakunrin rẹ̀;


O si fun u ni majẹmu ikọlà: bẹ̃li Abrahamu bí Isaaki, o kọ ọ ni ilà ni ijọ kẹjọ; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bi awọn baba nla mejila.


Bẹ̃ni kì iṣe pe, nitori nwọn jẹ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn li ọmọ: ṣugbọn, ninu Isaaki li a ó ti pè irú-ọmọ rẹ.


Niti ẹniti a wipe, Ninu Isaaki li a o ti pè irú-ọmọ rẹ:


Emi si mú Abrahamu baba nyin lati ìha keji Odò na wá, mo si ṣe amọ̀na rẹ̀ là gbogbo ilẹ Kenaani já, mo si sọ irú-ọmọ rẹ̀ di pipọ̀, mo si fun u ni Isaaki.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan